Isa 45:1-7
Isa 45:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
BAYI ni Oluwa wi fun ẹni-ororo rẹ̀, fun Kirusi, ẹniti mo di ọwọ́ ọtún rẹ̀ mu, lati ṣẹ́gun awọn orilẹ-ède niwaju rẹ̀; emi o si tú amure ẹgbẹ awọn ọba, lati ṣi ilẹkùn mejeji niwaju rẹ̀, a ki yio si tì ẹnu-bode na; Emi o lọ siwaju rẹ, emi o si sọ ibi wiwọ́ wọnni di titọ́: emi o fọ ilẹkùn idẹ wọnni tũtũ, emi o si ke ọjá-irin si meji. Emi o si fi iṣura okùnkun fun ọ, ati ọrọ̀ ti a pamọ nibi ikọkọ, ki iwọ le mọ̀ pe, emi Oluwa, ti o pè ọ li orukọ rẹ, li Ọlọrun Israeli. Nitori Jakobu iranṣẹ mi, ati Israeli ayanfẹ mi, emi ti pè ọ li orukọ rẹ: mo ti fi apele kan fun ọ, bi iwọ ko tilẹ ti mọ̀ mi. Emi li Oluwa, ko si ẹlomiran, kò si Ọlọrun kan lẹhin mi: mo dì ọ li àmure, bi iwọ kò tilẹ ti mọ̀ mi. Ki nwọn le mọ̀ lati ila-õrun, ati lati iwọ-õrun wá pe, ko si ẹnikan lẹhin mi; Emi ni Oluwa, ko si ẹlomiran. Mo dá imọlẹ, mo si dá okunkun: mo ṣe alafia, mo si dá ibi: Emi Oluwa li o ṣe gbogbo wọnyi.
Isa 45:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Ohun tí OLUWA sọ fún kirusi, ẹni tí ó fi àmì òróró yàn nìyí: Ẹni tí OLUWA di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, tí ó lò, láti rẹ àwọn orílẹ̀-èdè sílẹ̀ níwájú rẹ̀, láti tú àmùrè àwọn ọba, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀, kí ẹnubodè má lè tì. OLUWA ní, “N óo lọ ṣáájú rẹ, n óo sọ àwọn òkè ńlá di pẹ̀tẹ́lẹ̀; n óo fọ́ ìlẹ̀kùn idẹ, n óo sì gé ọ̀pá ìlẹ̀kùn irin. N óo fún ọ ní ìṣúra tí wọ́n fi pamọ́ sinu òkùnkùn, ati àwọn nǹkan tí wọ́n kó pamọ́ síkọ̀kọ̀; kí o lè mọ̀ pé èmi, OLUWA, Ọlọrun Israẹli, ni mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ. Nítorí Jakọbu, iranṣẹ mi, ati Israẹli, àyànfẹ́ mi, mo pè ọ́ ní orúkọ rẹ. Mo pe orúkọ rẹ ní àpèjá, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ mí. “Èmi ni OLUWA kò sí ẹlòmíràn, kò sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi. Mo dì ọ́ ní àmùrè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò mọ̀ mí. Kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi ni OLUWA, kò tún sí ẹlòmíràn. Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn, èmi ni mo dá alaafia ati àjálù: Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.
Isa 45:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èyí ni ohun tí OLúWA sọ fún ẹni òróró rẹ̀, sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀ àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn, láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà. Èmi yóò lọ síwájú rẹ èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ èmi ó sì gé ọ̀pá irin. Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn, ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin, Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ. Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi àti Israẹli ẹni tí mo yàn Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ, mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí. Èmi ni OLúWA, àti pé kò sí ẹlòmíràn; yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan, Èmi yóò fún ọ ní okun, bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí, tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. Èmi ni OLúWA, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́. Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù; Èmi OLúWA ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.