Isa 44:21-23
Isa 44:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ranti wọnyi, Jakobu ati Israeli; nitori iwọ ni iranṣẹ mi: Emi ti mọ ọ; iranṣẹ mi ni iwọ, Israeli; iwọ ki yio di ẹni-igbagbe lọdọ mi. Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada. Kọrin, ẹnyin ọrun; nitori Oluwa ti ṣe e: kigbe, ẹnyin isalẹ aiye; bú si orin, ẹnyin oke-nla, igbó, ati gbogbo igi inu rẹ̀; nitori Oluwa ti rà Jakobu pada, o si ṣe ara rẹ̀ logo ni Israeli.
Isa 44:21-23 Yoruba Bible (YCE)
Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi, nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli. Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́, n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli. Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma, mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu. Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada. Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é. Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀, nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada, yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli.
Isa 44:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli. Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ. Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.” Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLúWA ló ti ṣe èyí; kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí OLúWA ti ra Jakọbu padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.