Isa 42:3-4
Isa 42:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iyè fifọ́ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹ̃fin ni on kì yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ. Ãrẹ̀ kì yio mú u, a kì yio si daiyà fò o, titi yio fi gbé idajọ kalẹ li aiye, awọn erekùṣu yio duro de ofin rẹ̀.
Isa 42:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú, yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́. Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì, títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé. Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.”
Isa 42:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá; òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé. Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.”