Isa 42:22
Isa 42:22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn enia ti a jà lole ti a si ko li ẹrù ni eyi: gbogbo wọn li a dẹkùn mu ninu ihò, a fi wọn pamọ ninu tubu: a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si gbà wọn; a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si wipe, Mu u pada.
Pín
Kà Isa 42Isa 42:22 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè, a sì ti kó wọn lẹ́rù, a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀, a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀, a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé: “Ẹ dá wọn pada.”
Pín
Kà Isa 42Isa 42:22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan nìyìí tí a jà lógun tí a sì kó lẹ́rú, gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun, tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n. Wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀; wọ́n ti di ìkógun, láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”
Pín
Kà Isa 42