Isa 42:10-13
Isa 42:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ kọ orin titun si Oluwa, iyìn rẹ̀ lati opin aiye, ẹnyin ti nsọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: erekùṣu, ati awọn ti ngbé inu wọn. Jẹ ki aginjù ati ilu-nla ibẹ gbé ohùn wọn soke, iletò wọnni ti Kedari ngbé: jẹ ki awọn ti ngbé apáta kọrin, jẹ ki wọn hó lati ori oke-nla wá. Jẹ ki wọn fi ogo fun Oluwa, ki wọn si wi iyìn rẹ̀ ninu erekùṣu. Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀.
Isa 42:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kọ orin tuntun sí OLUWA; ẹ kọ orin ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé. Ẹ̀yin èrò inú ọkọ̀ lójú agbami òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu omi òkun; ati àwọn erékùṣù ati àwọn tí ń gbé inú wọn. Kí aṣálẹ̀ ati àwọn ìlú inú rẹ̀ kọ orin ìyìn sókè, ati àwọn abúlé agbègbè Kedari; kí àwọn ará ìlú Sela kọrin ayọ̀, kí wọn máa kọrin lórí àwọn òkè. Kí wọn fi ògo fún OLUWA, kí wọn kéde ìyìn rẹ̀ ní àwọn erékùṣù. OLUWA yọ jáde lọ bí alágbára ọkunrin, ó ru ibinu rẹ̀ sókè bí ọkunrin ogun, ó kígbe, ó sì bú ramúramù. Ó fihàn pé alágbára ni òun níwájú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Isa 42:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ orin tuntun sí OLúWA ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn. Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn igi Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè. Jẹ́ kí wọn fi ògo fún OLúWA àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù. OLúWA yóò rìn jáde gẹ́gẹ́ bí i ọkùnrin alágbára, yóò ru owú sókè bí ológun; yóò kígbe nítòótọ́, òun yóò ké igbe ogun, òun yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀.