Isa 42:1-9

Isa 42:1-9 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní, “Wo iranṣẹ mi, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi, ẹni tí inú mi dùn sí. Mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí mi bà lé e, yóo máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè. Kò ní kígbe, kò sì ní pariwo, kò ní jẹ́ kí á gbọ́ ohùn rẹ̀ ní ìta gbangba. Kò ní ṣẹ́ ọ̀pá ìyè tí ó tẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pa iná fìtílà tí ń jò bẹ́lúbẹ́lú, yóo fi òtítọ́ dá ẹjọ́. Kò ní kùnà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì, títí yóo fi fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ láyé. Àwọn erékùṣù ń retí òfin rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ; ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ, tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀; ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀; tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀. Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo, mo ti di ọwọ́ rẹ mú, mo sì pa ọ́ mọ́. Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé, mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè; kí o lè la ojú àwọn afọ́jú, kí o lè yọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kúrò ni àhámọ́, kí o lè yọ àwọn tí ó jókòó ninu òkùnkùn kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. “Èmi ni OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni orúkọ mi; n kò ní fi ògo mi fún ẹlòmíràn, n kò sì ní fi ìyìn mi fún ère. Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá, àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii. Kí wọn tó yọjú jáde rárá, ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.”

Isa 42:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀; Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè. Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè, tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà. Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá; òun kì yóò kọsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní rẹ̀wẹ̀sì títí tí yóò fi fi ìdájọ́ múlẹ̀ ní ayé. Nínú òfin rẹ̀ ni àwọn erékùṣù yóò fi ìrètí wọn sí.” Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run wí Ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run tí ó sì tẹ́ wọ́n sóde, tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tí ó jáde nínú wọn, Ẹni tí ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní èémí àti ẹ̀mí fún gbogbo àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀: “Èmi, OLúWA, ti pè ọ́ ní òdodo; Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn. “Èmi ni OLúWA; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà. Kíyèsi i, àwọn nǹkan àtijọ́ ti wáyé, àti àwọn nǹkan tuntun ni mo ti wí pé; kí wọn tó hù jáde mo ti kéde rẹ̀ fún ọ.”

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa