Isa 41:8-16

Isa 41:8-16 Yoruba Bible (YCE)

“Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi, Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn, ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi. Ìwọ tí mo mú wá láti òpin ayé, tí mo pè láti ìkangun ayé tí ó jìnnà jùlọ, mo wí fún ọ pé, ‘Iranṣẹ mi ni ọ́, mo ti yàn ọ́, n kò ní ta ọ́ nù.’ Má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, má fòyà, nítorí èmi ni Ọlọrun rẹ. N óo fún ọ ní agbára, n óo sì ràn ọ́ lọ́wọ́; ọwọ́ ọ̀tún mi, ọwọ́ ìṣẹ́gun, ni n óo fi gbé ọ ró. “Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́ run ni n óo dójú tì, wọn óo sì dààmú. Àwọn tí ń bá ọ jà yóo di asán, wọn óo sì ṣègbé. O óo wá àwọn tí ń bá ọ jà tì, o kò ní rí wọn. Àwọn tí ó gbógun tì ọ́ yóo di òfo patapata. Nítorí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ, ti di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, èmi ni mo sọ fún ọ pé kí o má bẹ̀rù, n óo ràn ọ́ lọ́wọ́.” Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, bí ẹ tilẹ̀ dàbí kòkòrò lásán, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA ní òun óo ràn yín lọ́wọ́. Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà yín. Ó ní, “N óo ṣe yín bí ohun èlò ìpakà titun, tí ó mú, tí ó sì ní eyín, ẹ óo tẹ àwọn òkè ńlá mọ́lẹ̀, ẹ óo rún wọn wómúwómú; ẹ óo sì sọ àwọn òkè kéékèèké di fùlùfúlù. Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ, ìjì yóo sì fọ́n wọn ká. Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.

Isa 41:8-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi, Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn, ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi, mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé, láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́. Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi;’ Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi. “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọ ni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà; àwọn tó ń bá ọ jà yóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ kì yóò rí wọn. Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́ yóò dàbí ohun tí kò sí. Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni OLúWA wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun, tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò. Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú, àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú OLúWA ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.