Isa 35:8-10
Isa 35:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i. Kiniun kì yio si nibẹ, bẹ̃ni ẹranko buburu kì yio gùn u, a kì yio ri i nibẹ; ṣugbọn awọn ti a ràpada ni yio ma rìn nibẹ: Awọn ẹni-iràpada Oluwa yio padà, nwọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri ayọ̀ ati inu didùn gbà, ikãnu on imí-ẹ̀dùn yio si fò lọ.
Isa 35:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀, a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́; nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá, àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀. Kò ní sí kinniun níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀. A kò ní rí wọn níbẹ̀, àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀. Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada, wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin, ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn. Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbà ìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.
Isa 35:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà, àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá. Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀, àwọn ẹni ìràpadà OLúWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.