Isa 35:3-7
Isa 35:3-7 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró. Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun. Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé: “Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù. Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san, ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun; ó ń bọ̀ wá gbà yín là.” Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà, etí adití yóo sì ṣí; arọ yóo máa fò bí ìgalà, odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀. Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjù àwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omi ilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi, ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà, èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀.
Isa 35:3-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun. Ẹ sọ fun awọn alailaiyà pe, ẹ tujuka, ẹ má bẹ̀ru: wò o, Ọlọrun nyin o wá ti on ti ẹsan, Ọlọrun ti on ti igbẹsan; on o wá, yio si gbà nyin. Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi. Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù. Ilẹ yíyan yio si di àbata, ati ilẹ ongbẹ yio di isun omi; ni ibugbé awọn dragoni, nibiti olukuluku dubulẹ, ni o jẹ ọgbà fun ẽsú on iyè.
Isa 35:3-7 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró. Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun. Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé: “Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù. Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san, ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun; ó ń bọ̀ wá gbà yín là.” Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà, etí adití yóo sì ṣí; arọ yóo máa fò bí ìgalà, odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀. Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjù àwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omi ilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi, ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà, èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀.
Isa 35:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun: Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.” Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀. Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà, ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi. Ní ibùgbé àwọn dragoni, níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀, ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.