Isa 35:1-10

Isa 35:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Inú aṣálẹ̀ ati ilẹ̀ gbígbẹ yóo dùn, aṣálẹ̀ yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo rúwé, yóo sì tanná. Nítòótọ́ yóo tanná bí òdòdó, yóo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, yóo sì kọrin. Ògo Lẹbanoni yóo di tìrẹ ati iyì Kamẹli ati ti Ṣaroni. Wọn óo rí ògo OLUWA, wọn óo rí ọlá ńlá Ọlọrun wa. Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró. Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun. Ẹ sọ fún àwọn tí àyà wọn ń já pé: “Ẹ ṣe ara gírí, ẹ má bẹ̀rù. Ẹ wò ó! Ọlọrun yín óo wá pẹlu ẹ̀san, ó ń bọ̀ wá gbẹ̀san gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun; ó ń bọ̀ wá gbà yín là.” Ojú afọ́jú yóo là nígbà náà, etí adití yóo sì ṣí; arọ yóo máa fò bí ìgalà, odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀. Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjù àwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omi ilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi, ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà, èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀. Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀, a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́; nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá, àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀. Kò ní sí kinniun níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀. A kò ní rí wọn níbẹ̀, àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀. Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada, wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin, ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn. Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbà ìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.

Isa 35:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn; aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná. Gẹ́gẹ́ bí ewéko, Ní títanná yóò tanná; yóò yọ ayọ̀ ńláńlá yóò sì kọrin. Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un, ẹwà Karmeli àti Ṣaroni; wọn yóò rí ògo OLúWA, àti ẹwà Ọlọ́run wa. Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun: Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.” Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀. Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà, ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi. Ní ibùgbé àwọn dragoni, níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀, ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi. Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà, àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá. Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀, àwọn ẹni ìràpadà OLúWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa