Isa 3:8-15
Isa 3:8-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori Jerusalemu di iparun, Juda si ṣubu: nitori ahọn wọn ati iṣe wọn lòdi si Oluwa, lati mu oju ogo rẹ̀ binu. Iwò oju wọn njẹri si wọn; nwọn si nfi ẹ̀ṣẹ wọn hàn bi Sodomu, nwọn kò pa a mọ. Egbe ni fun ọkàn wọn! nitori nwọn ti fi ibi san a fun ara wọn. Ẹ sọ fun olododo pe, yio dara fun u: nitori nwọn o jẹ eso iṣe wọn. Egbe ni fun enia buburu! yio buru fun u: nitori ere ọwọ́ rẹ̀ li a o fi fun u. Niti awọn enia mi awọn ọmọde ni aninilara wọn, awọn obinrin si njọba wọn. A! enia mi, awọn ti nyẹ ọ si mu ọ ṣìna, nwọn si npa ipa-ọ̀na rẹ run. Oluwa dide duro lati wijọ, o si dide lati da awọn enia li ẹjọ. Oluwa yio ba awọn agbà enia rẹ̀ lọ sinu idajọ, ati awọn ọmọ-alade inu wọn: nitori ẹnyin ti jẹ ọ̀gba àjara nì run: ẹrù awọn talakà mbẹ ninu ile nyin. Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Kili ẹnyin rò ti ẹ fi fọ́ awọn enia mi tutu, ti ẹ si fi oju awọn talakà rinlẹ?
Isa 3:8-15 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀, Juda sì ti ṣubú. Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA, wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀. Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n; wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu: Wọn kò fi bò rárá. Ègbé ni fún wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn. Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọn nítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn. Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú, kò ní dára fún wọn. Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ẹ wá wo àwọn eniyan mi! Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi; àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí. Ẹ̀yin eniyan mi, àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà, wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú. OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀; ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́ OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀ siwaju ìtẹ́ ìdájọ́, yóo sọ fún wọn pé; “Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run, ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín. Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?”
Isa 3:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n Juda ń ṣubú lọ, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí OLúWA, láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú. Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn. Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn, nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn. Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn. Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí. Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà, wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín. OLúWA bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́ Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́. OLúWA dojú ẹjọ́ kọ àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀. “Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín. Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?” ni Olúwa wí, OLúWA àwọn ọmọ-ogun.