Isa 3:1-26

Isa 3:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

KIYESI i, Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, mu idaduro ati ọpá kuro ninu Jerusalemu ati Juda, gbogbo idaduro onjẹ, ati gbogbo idaduro omi. Alagbara ọkunrin, ati jagunjagun, onidajọ, ati wolĩ, ati amoye, ati agbà. Balogun ãdọta, ati ọkunrin ọlọla, ati igbìmọ, ati oniṣọ̀na, ati alasọdùn. Awọn ọmọde li emi o fi ṣe ọmọ-alade wọn, awọn ọmọ-ọwọ ni yio si ma ṣe akoso wọn. A o si ni awọn enia lara, olukuluku lọwọ ẹnikeji, ati olukuluku lọwọ aladugbo rẹ̀; ọmọde yio huwà igberaga si àgba, ati alailọla si ọlọla. Nigbati enia kan yio di arakunrin rẹ̀ ti ile baba rẹ̀ mu, wipe, Iwọ ni aṣọ, mã ṣe alakoso wa, ki o si jẹ ki iparun yi wà labẹ ọwọ́ rẹ. Lọjọ na ni yio bura, wipe, Emi kì yio ṣe alatunṣe; nitori ni ile mi kò si onjẹ tabi aṣọ: máṣe fi emi ṣe alakoso awọn enia. Nitori Jerusalemu di iparun, Juda si ṣubu: nitori ahọn wọn ati iṣe wọn lòdi si Oluwa, lati mu oju ogo rẹ̀ binu. Iwò oju wọn njẹri si wọn; nwọn si nfi ẹ̀ṣẹ wọn hàn bi Sodomu, nwọn kò pa a mọ. Egbe ni fun ọkàn wọn! nitori nwọn ti fi ibi san a fun ara wọn. Ẹ sọ fun olododo pe, yio dara fun u: nitori nwọn o jẹ eso iṣe wọn. Egbe ni fun enia buburu! yio buru fun u: nitori ere ọwọ́ rẹ̀ li a o fi fun u. Niti awọn enia mi awọn ọmọde ni aninilara wọn, awọn obinrin si njọba wọn. A! enia mi, awọn ti nyẹ ọ si mu ọ ṣìna, nwọn si npa ipa-ọ̀na rẹ run. Oluwa dide duro lati wijọ, o si dide lati da awọn enia li ẹjọ. Oluwa yio ba awọn agbà enia rẹ̀ lọ sinu idajọ, ati awọn ọmọ-alade inu wọn: nitori ẹnyin ti jẹ ọ̀gba àjara nì run: ẹrù awọn talakà mbẹ ninu ile nyin. Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Kili ẹnyin rò ti ẹ fi fọ́ awọn enia mi tutu, ti ẹ si fi oju awọn talakà rinlẹ? Pẹlupẹlu Oluwa wipe, Nitori awọn ọmọbinrin Sioni gberaga, ti nwọn si nrìn pẹlu ọrùn giga ati oju ifẹkufẹ, ti nwọn nrìn ti nwọn si nyan bi nwọn ti nlọ, ti nwọn si njẹ ki ẹsẹ wọn ró woro: Nitorina Oluwa yio fi ẽpá lu atàri awọn ọmọbinrin Sioni, Oluwa yio si fi ihoho wọn hàn. Li ọjọ na Oluwa yio mu ogo ṣaworo wọn kuro, ati awọn ọṣọ́ wọn, ati iweri wọn bi oṣupa. Ati ẹ̀wọn, ati jufù, ati ìboju, Ati akẹtẹ̀, ati ohun ọṣọ́-ẹsẹ, ati ọjá-ori, ati ago olõrùn didùn, ati oruka eti, Oruka, ati ọṣọ́-imu, Ipãrọ̀ aṣọ wiwọ, ati aṣọ ilekè, ati ibọ̀run, ati àpo, Awòjiji, ati aṣọ ọ̀gbọ daradara, ati ibòri ati ibòju, Yio si ṣe pe, õrun buburu yio wà dipò õrun didùn; akisà ni yio si dipò amùre; ori pipá ni yio si dipò irun didì daradara; sisan aṣọ ọ̀fọ dipò igbaiya, ijoná yio si dipò ẹwà. Awọn ọkunrin rẹ yio ti ipa idà ṣubu, ati awọn alagbara rẹ loju ogun. Awọn bodè rẹ̀ yio pohùnrere ẹkun, nwọn o si ṣọ̀fọ; ati on, nitori o di ahoro, yio joko ni ilẹ.

Isa 3:1-26 Yoruba Bible (YCE)

Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo mú gbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò, ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda. Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé, ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀. Yóo mú àwọn alágbára ati àwọn ọmọ ogun kúrò, pẹlu àwọn onídàájọ́ ati àwọn wolii, àwọn aláfọ̀ṣẹ ati àwọn àgbààgbà; àwọn olórí aadọta ọmọ ogun, ati àwọn ọlọ́lá, àwọn adáhunṣe ati àwọn pidánpidán, ati àwọn olóògùn. Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn, àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn. Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn, olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀, àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn. Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá. Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀, ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé, “Ìwọ ní aṣọ ìlékè, nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa; gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.” Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé, “Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe. N kò ní oúnjẹ nílé bẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ. Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.” Nítorí Jerusalẹmu ti kọsẹ̀, Juda sì ti ṣubú. Nítorí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ati ìṣe wọn lòdì sí OLUWA, wọ́n ń tàpá sí ògo wíwà rẹ̀. Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n; wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu: Wọn kò fi bò rárá. Ègbé ni fún wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn. Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọn nítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn. Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú, kò ní dára fún wọn. Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ẹ wá wo àwọn eniyan mi! Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi; àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí. Ẹ̀yin eniyan mi, àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà, wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú. OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀; ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́ OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀ siwaju ìtẹ́ ìdájọ́, yóo sọ fún wọn pé; “Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run, ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín. Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?” OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga, bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan; wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ. Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dún bí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá; yóo ṣí aṣọ lórí wọn.” Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn; ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn. Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn, òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá. Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara, okùn yóo wà dípò ọ̀já; orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye. Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà. Idà ni yóo pa àwọn ọkunrin yín, àwọn akikanju yín yóo kú sógun. Ọ̀fọ̀ ati ẹkún yóo pọ̀ ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu. Yóo dàbí obinrin tí wọ́n tú sí ìhòòhò, tí ó jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

Isa 3:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kíyèsi i, Olúwa, OLúWA àwọn ọmọ-ogun, fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jerusalẹmu àti Juda gbogbo ìpèsè oúnjẹ àti ìpèsè omi. Àwọn akíkanjú àti jagunjagun, adájọ́ àti wòlíì, aláfọ̀ṣẹ àti alàgbà, balógun àádọ́ta àti àwọn ènìyàn, onípò gíga olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ àti ògbójú oníṣègùn. “Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn, ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì máa jẹ ọba lórí i wọn.” Àwọn ènìyàn yóò sì máa pọ́n ọmọnìkejì wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbógun ti àwọn àgbàgbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí ọlọ́lá. Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ mú, nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé, “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa, sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!” Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé, “Èmi kò ní àtúnṣe kan. Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ó ní aṣọ nílé, ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.” Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n Juda ń ṣubú lọ, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí OLúWA, láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú. Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn. Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn, nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn. Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn. Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí. Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà, wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín. OLúWA bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́ Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́. OLúWA dojú ẹjọ́ kọ àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀. “Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín. Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?” ni Olúwa wí, OLúWA àwọn ọmọ-ogun. OLúWA wí pé, “Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn. Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni, OLúWA yóò sì pá wọn ní agbárí.” Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú, gbogbo gèlè, ẹ̀gbà ọrùn, ẹsẹ̀ àti àyà, àwọn ìgò tùràrí àti òògùn, òrùka ọwọ́ àti ti imú, àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́, Dígí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú. Dípò òórùn dídùn, òórùn búburú ni yóò wá, okùn ni yóò wà dípò àmùrè, orí pípá ni yóò dípò irun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà. Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú, àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun. Àwọn bodè Sioni yóò sọkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀, nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.