Isa 25:7-9
Isa 25:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li oke-nla yi on o si pa iboju ti o bò gbogbo enia loju run, ati iboju ti a nà bò gbogbo orilẹ-ède. On o gbe iku mì lailai; Oluwa Jehofah yio nù omije nù kuro li oju gbogbo enia; yio si mu ẹ̀gan enia rẹ̀ kuro ni gbogbo aiye: nitori Oluwa ti wi i. A o si sọ li ọjọ na pe, Wò o, Ọlọrun wa li eyi; awa ti duro de e, on o si gbà wa là: Oluwa li eyi: awa ti duro de e, awa o ma yọ̀, inu wa o si ma dùn ninu igbala rẹ̀.
Isa 25:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.”
Isa 25:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀; Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. OLúWA Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn; Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLúWA ni ó ti sọ ọ́. Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni OLúWA, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”