Isa 25:4-9
Isa 25:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori iwọ ti jẹ agbara fun talaka, agbara fun alaini ninu iṣẹ́ rẹ̀, ãbo kuro ninu ìji, ojiji kuro ninu oru, nigbati ẹfũfu lile awọn ti o ni ibẹ̀ru dabi ìji lara ogiri. Iwọ o mu ariwo awọn alejo rọlẹ, gẹgẹ bi oru nibi gbigbẹ; ani oru pẹlu ojiji awọsanma: a o si rẹ̀ orin-ayọ̀ awọn ti o ni ibẹ̀ru silẹ. Ati ni oke-nla yi li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sè asè ohun abọ́pa fun gbogbo orilẹ-ède, asè ọti-waini lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ, ti ohun abọpa ti o kún fun ọra, ti ọti-waini ti o tòro lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ. Li oke-nla yi on o si pa iboju ti o bò gbogbo enia loju run, ati iboju ti a nà bò gbogbo orilẹ-ède. On o gbe iku mì lailai; Oluwa Jehofah yio nù omije nù kuro li oju gbogbo enia; yio si mu ẹ̀gan enia rẹ̀ kuro ni gbogbo aiye: nitori Oluwa ti wi i. A o si sọ li ọjọ na pe, Wò o, Ọlọrun wa li eyi; awa ti duro de e, on o si gbà wa là: Oluwa li eyi: awa ti duro de e, awa o ma yọ̀, inu wa o si ma dùn ninu igbala rẹ̀.
Isa 25:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka, ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro. Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò, ati ìbòòji ninu oòrùn. Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiri bẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí; ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀. O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́; bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́, bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára. Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀. Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.”
Isa 25:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù. O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì, gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́. Ní orí òkè yìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèsè àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì tí ó gbámúṣé. Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀; Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. OLúWA Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn; Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLúWA ni ó ti sọ ọ́. Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni OLúWA, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”