Isa 1:1-9
Isa 1:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
IRAN Isaiah ọmọ Amosi, ti o rí nipa Juda ati Jerusalemu li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda. Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi. Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu. A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn. Ẽṣe ti a o fi lù nyin si i mọ? ẹnyin o ma ṣọ̀tẹ siwaju ati siwaju: gbogbo ori li o ṣaisàn, gbogbo ọkàn li o si dakú. Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn. Ilẹ nyin di ahoro, a fi iná kun ilu nyin: ilẹ nyin, alejo jẹ ẹ run li oju nyin, o si di ahoro, bi eyiti awọn alejo wó palẹ. Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti. Bikòṣe bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra.
Isa 1:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ìran tí Aisaya ọmọ Amosi rí sí Juda ati Jerusalẹmu nìyí, nígbà ayé Usaya, Jotamu, Ahasi, ati Hesekaya, àwọn ọba Juda. Máa gbọ́, ìwọ ọ̀run, sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé Nítorí pé OLUWA ń sọ̀rọ̀ Ó ní, “Lẹ́yìn tí mo bọ́ àwọn ọmọ, tí mo tọ́ wọn dàgbà tán, ọ̀tẹ̀ ni wọ́n dì sí mi. Mààlúù mọ olówó rẹ̀; kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sí mọ ibùjẹ tí oluwa rẹ̀ ṣe fún un; ṣugbọn Israẹli kò mọ nǹkan, òye kò yé àwọn eniyan mi.” Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ, ìran oníṣẹ́ ibi; àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́! Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹli wọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i. Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni, àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò, gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín, kò síbìkan tí ó gbádùn. Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn. Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro, wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín. Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín. Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀. Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà, ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí; ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì. Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni, à bá rí bí i Sodomu, à bá sì dàbí Gomora.
Isa 1:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda. Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé! Nítorí OLúWA ti sọ̀rọ̀: “Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Màlúù mọ olówó rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀, òye kò yé àwọn ènìyàn mi.” Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù, Ìran àwọn aṣebi, àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́! Wọn ti kọ OLúWA sílẹ̀ wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn sì ti kẹ̀yìn sí i. Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́? Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́, gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró. Orílẹ̀-èdè yín dahoro, a dáná sun àwọn ìlú yín, oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run lójú ara yín náà, ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí àwọn àjèjì borí rẹ̀. Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà, gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí, àti bí ìlú tí a dó tì. Àyàfi bí OLúWA àwọn ọmọ-ogun bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà, a ò bá ti rí bí Sodomu, a ò bá sì ti dàbí Gomorra.