Heb 9:11-15
Heb 9:11-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi. Bẹ̃ni kì iṣe nipasẹ ẹ̀jẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹ̀jẹ on tikararẹ̀ o wọ ibi mimọ́ lẹ̃kanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gbà fun wa. Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara, Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye? Ati nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà.
Heb 9:11-15 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Kristi ti dé, òun sì ni Olórí Alufaa àwọn ohun rere tí ó wà. Ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ninu àgọ́ tí ó pé tí ó sì tóbi ju ti àtijọ́ lọ, àgọ́ tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí kì í sì í ṣe ti ẹ̀dá ayé yìí. Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ tabi ti mààlúù bíkòṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀, ni ó fi rúbọ, nígbà tí ó wọ inú Ibi Mímọ́ jùlọ lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ṣe ìràpadà ayérayé fún wa. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ ati ti mààlúù ati eérú abo mààlúù tí a bù wọ́n àwọn tí wọ́n bá ṣe ohun èérí nípa ẹ̀sìn bá sọ wọ́n di mímọ́ lóde ara, mélòó-mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ tí kò lábùkù sí Ọlọrun nípa Ẹ̀mí ayérayé, yóo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu iṣẹ́ tíí yọrí sí ikú, tí yóo sì fi ṣe wá yẹ fún ìsìn Ọlọrun alààyè. Nítorí èyí, òun ni alárinà majẹmu. Ó kú kí ó lè ṣe ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan dá lábẹ́ majẹmu àkọ́kọ́, kí àwọn tí Ọlọrun pè lè gba ìlérí ogún ayérayé.
Heb 9:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi dé bí olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípasẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, (èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí), Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkára rẹ̀, o wọ ibi mímọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eérú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọ ni di mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara: mélòó mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè? Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ìlérí ogún àìnípẹ̀kun gbà.