Heb 6:9-12
Heb 6:9-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn, olufẹ, awa ni igbagbọ ohun ti o dara jù bẹ̃ lọ niti nyin, ati ohun ti o faramọ igbala, bi awa tilẹ nsọ bayi. Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe. Awa si fẹ ki olukuluku nyin ki o mã fi irú aisimi kanna hàn, fun ẹ̀kún ireti titi de opin: Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri.
Heb 6:9-12 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sọ̀rọ̀ báyìí, sibẹ ó dá wa lójú nípa tiyín, ẹ̀yin àyànfẹ́, pé ipò yín dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní ohun tí ó yẹ fún ìgbàlà. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii. Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí olukuluku yín fi ìtara kan náà hàn, tí ẹ fi lè ní ẹ̀kún ìrètí yín títí dé òpin; kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun.
Heb 6:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin: Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.