Heb 6:7-8
Heb 6:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ilẹ ti o fi omi ojò ti nrọ̀ sori rẹ̀ nigbagbogbo mu, ti o si nhù ewebẹ ti o dara fun awọn ti a nti itori wọn ro o pẹlu, ngbà ibukún lọwọ Ọlọrun. Ṣugbọn eyiti o nhù ẹgún ati oṣuṣu, a kọ̀ ọ, kò si jìna si egún; opin eyiti yio jẹ fun ijona.
Heb 6:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni. Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún.
Heb 6:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná.