Heb 6:10-19

Heb 6:10-19 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii. Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí olukuluku yín fi ìtara kan náà hàn, tí ẹ fi lè ní ẹ̀kún ìrètí yín títí dé òpin; kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun. Nítorí nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu, ara rẹ̀ ni ó fi búra nígbà tí kò sí ẹnìkan tí ó tóbi bíi rẹ̀ tí ìbá fi búra. Ó ní, “Ní ti ibukun, n óo bukun ọ. Ní ti kí eniyan pọ̀, n óo sọ ọ́ di pupọ.” Bẹ́ẹ̀ ni Abrahamu ṣe gba ìlérí náà pẹlu sùúrù. Ẹni tí ó bá juni lọ ni a fi í búra. Ọ̀rọ̀ tí eniyan bá sì ti búra lé lórí, kò sí àríyànjiyàn lórí rẹ̀ mọ́. Ní ọ̀nà kan náà, nígbà tí Ọlọrun fẹ́ fihàn gbangba fún àwọn ajogún ìlérí wí pé èrò òun kò yipada, ó ṣe ìlérí, ó sì fi ìbúra tì í. Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú. A di ìlérí náà mú. Ó dàbí ìdákọ̀ró fún ọkàn wa. Ìlérí yìí dájú, ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Ó ti wọ inú yàrá tí ó wà ninu, lẹ́yìn aṣọ ìkélé

Heb 6:10-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin: Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí. Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Abrahamu, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé, “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.” Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà. Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀. Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin: Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé

Heb 6:10-19

Heb 6:10-19 YBCV