Heb 3:12-13
Heb 3:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ́ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye. Ṣugbọn ẹ mã gbà ara nyin niyanju li ojojumọ́, niwọn igbati a ba npè e ni Oni, ki a má bã sé ọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ.
Heb 3:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kíyèsára, ará, kí ó má ṣe sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo ní inú burúkú tóbẹ́ẹ̀ ti kò ní ní igbagbọ, tí yóo wá pada kúrò lẹ́yìn Ọlọrun alààyè. Ṣugbọn ẹ máa gba ara yín níyànjú lojoojumọ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ “Òní” tí Ìwé Mímọ́ sọ bá ti bá àwa náà wí, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà tan ẹnikẹ́ni lọ, kí ó sì mú kí ó ṣe agídí sí Ọlọrun.
Heb 3:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.