Heb 2:5-9
Heb 2:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe ki iṣe abẹ awọn angẹli li o fi aiye ti mbọ̀ ti awa nsọrọ rẹ̀ si. Ṣugbọn ẹnikan sọ nibikan wipe, Kili enia ti o fi nṣe iranti rẹ̀, tabi ọmọ enia, ti o mbẹ̀ ẹ wò? Iwọ dá a rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ; iwọ fi ogo ati ọlá dé e li ade, iwọ si fi i jẹ olori iṣẹ ọwọ́ rẹ: Iwọ fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Nitori niti pe o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ kò kù ohun kan ti kò fi sabẹ rẹ̀. Ṣugbọn nisisiyi awa kò iti ri pe a fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀. Awa ri ẹniti a dá rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ, ani Jesu, ẹniti a fi ogo ati ọlá dé li ade nitori ijiya ikú; ki o le tọ́ iku wò fun olukuluku enia nipa õre-ọfẹ Ọlọrun.
Heb 2:5-9 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí kì í ṣe àwọn angẹli ni ó fún ní àṣẹ láti ṣe àkóso ayé tí ń bọ̀, èyí tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó wà ní àkọsílẹ̀ níbi tí ẹnìkan ti sọ pé, “Kí ni eniyan, tí o fi ń ranti rẹ̀, tabi ọmọ eniyan tí o fi ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀? O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀. O sì fi ògo ati ọlá dé e ládé. O fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Nítorí pé ó fi gbogbo nǹkan wọnyi sí ìkáwọ́ rẹ̀, kò ku nǹkankan tí kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ṣugbọn nígbà náà, a kò ì tíì rí i, pé gbogbo nǹkan ni ó ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ṣugbọn a rí Jesu, tí Ọlọrun fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli fún àkókò díẹ̀. Òun ni ó jẹ oró ikú, tí Ọlọrun tún wá fi ògo ati ọlá dé e ládé. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ó kú fún gbogbo eniyan.
Heb 2:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé: “Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò? Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ; ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé, ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ: Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.