Heb 2:17-18
Heb 2:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina o yẹ pe ninu ohun gbogbo ki o dabi awọn ará rẹ̀, ki o le jẹ alãnu ati olõtọ Olori Alufa ninu ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le ṣe etutu fun ẹ̀ṣẹ awọn enia. Nitori niwọnbi on tikararẹ̀ ti jiya nipa idanwo, o le ràn awọn ti a ndan wo lọwọ.
Heb 2:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, dandan ni kí òun alára jọ àwọn arakunrin rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, kí ó lè jẹ́ Olórí Alufaa tí ó láàánú, tí ó sì ṣe é gbójú lé nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ níwájú Ọlọrun fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan. Nítorí níwọ̀n ìgbà tí òun alára ti jìyà, ó lè ran àwọn tí wọ́n wà ninu ìdánwò lọ́wọ́.
Heb 2:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.