Heb 2:10-16
Heb 2:10-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe o yẹ fun u, nitori ẹniti ohun gbogbo ṣe wà, ati nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ni mimu awọn ọmọ pupọ̀ wá sinu ogo, lati ṣe balogun igbala wọn li aṣepé nipa ìjiya. Nitori ati ẹniti nsọni di mimọ́ ati awọn ti a nsọ di mimọ́, lati ọdọ ẹnikanṣoṣo ni gbogbo wọn: nitori eyiti ko ṣe tiju lati pè wọn ni arakunrin, Wipe, Emi ó sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn ará mi, li ãrin ijọ li emi o kọrin iyìn rẹ. Ati pẹlu, Emi o gbẹkẹ̀ mi le e. Ati pẹlu, Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Ọlọrun fifun mi. Njẹ niwọn bi awọn ọmọ ti ṣe alabapin ara on ẹ̀jẹ, bẹ̃ gẹgẹ li on pẹlu si ṣe alabapin ninu ọkanna; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu; Ki o si le gbà gbogbo awọn ti o ti itori ibẹru iku wà labẹ ìde lọjọ aiye wọn gbogbo. Nitoripe, nitõtọ ki iṣe awọn angẹli li o ṣe iranlọwọ fun, ṣugbọn irú-ọmọ Abrahamu li o ṣe iranlọwọ fun.
Heb 2:10-16 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ. Nítorí ọ̀kan ni ẹni tí ó ń ya eniyan sí mímọ́ ati àwọn eniyan tí ó ń yà sí mímọ́ jẹ́, nítorí náà ni Jesu kò fi tijú láti pè wọ́n ní arakunrin rẹ̀. Ó ní, “Èmi óo pe orúkọ rẹ ní gbangba fún àwọn arakunrin mi. Ní ààrin àwùjọ ni n óo yìn ọ́.” Ó tún sọ pé, “Èmi ní tèmi, èmi óo gbẹ́kẹ̀lé e.” Ati pé, “Èmi nìyí ati àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi fún mi.” Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀, Jesu pàápàá di ẹlẹ́ran-ara ati ẹlẹ́jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wọn, kí ó lè ti ipasẹ̀ ikú rẹ̀ sọ agbára Satani tí ó ní ikú ní ìkáwọ́ di asán. Ó wá dá àwọn tí ẹ̀rù ikú ti sọ di ẹrú ninu gbogbo ìgbé-ayé wọn sílẹ̀. Nítorí ó dájú pé, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún bíkòṣe àwọn ọmọ Abrahamu.
Heb 2:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà. Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. Àti wí pé, “Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi, ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.” Àti pẹ̀lú, “Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.” Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù. Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún.