Heb 2:10-13
Heb 2:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe o yẹ fun u, nitori ẹniti ohun gbogbo ṣe wà, ati nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ni mimu awọn ọmọ pupọ̀ wá sinu ogo, lati ṣe balogun igbala wọn li aṣepé nipa ìjiya. Nitori ati ẹniti nsọni di mimọ́ ati awọn ti a nsọ di mimọ́, lati ọdọ ẹnikanṣoṣo ni gbogbo wọn: nitori eyiti ko ṣe tiju lati pè wọn ni arakunrin, Wipe, Emi ó sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn ará mi, li ãrin ijọ li emi o kọrin iyìn rẹ. Ati pẹlu, Emi o gbẹkẹ̀ mi le e. Ati pẹlu, Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Ọlọrun fifun mi.
Heb 2:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ. Nítorí ọ̀kan ni ẹni tí ó ń ya eniyan sí mímọ́ ati àwọn eniyan tí ó ń yà sí mímọ́ jẹ́, nítorí náà ni Jesu kò fi tijú láti pè wọ́n ní arakunrin rẹ̀. Ó ní, “Èmi óo pe orúkọ rẹ ní gbangba fún àwọn arakunrin mi. Ní ààrin àwùjọ ni n óo yìn ọ́.” Ó tún sọ pé, “Èmi ní tèmi, èmi óo gbẹ́kẹ̀lé e.” Ati pé, “Èmi nìyí ati àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi fún mi.”
Heb 2:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà. Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. Àti wí pé, “Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi, ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.” Àti pẹ̀lú, “Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.” Àti pẹ̀lú, “Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”