Heb 13:17
Heb 13:17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin.
Pín
Kà Heb 13Heb 13:17 Yoruba Bible (YCE)
Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani.
Pín
Kà Heb 13