Heb 13:1-25

Heb 13:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

KI ifẹ ará ki o wà titi. Ẹ máṣe gbagbé lati mã ṣe alejò; nitoripe nipa bẹ̃ li awọn ẹlomiran ṣe awọn angẹli li alejò laimọ̀. Ẹ mã ranti awọn onde bi ẹniti a dè pẹlu wọn, ati awọn ti a npọn loju bi ẹnyin tikaranyin pẹlu ti mbẹ ninu ara. Ki igbéyawo ki o li ọla larin gbogbo enia, ki akete si jẹ alailẽri: nitori awọn àgbere ati awọn panṣaga li Ọlọrun yio dá lẹjọ. Ki ọkàn nyin ki o máṣe fa si ifẹ owo, ki ohun ti ẹ ni ki o to nyin; nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ. Nitorina ni awa ṣe nfi igboiya wipe, Oluwa li oluranlọwọ mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi? Ẹ mã ranti awọn ti nwọn jẹ olori nyin, ti nwọn ti sọ ọ̀rọ Ọlọrun fun nyin; ki ẹ mã ro opin ìwa-aiye wọn, ki ẹ si mã ṣe afarawe igbagbọ́ wọn. Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai. Ẹ máṣe jẹ ki a fi onirũru ati ẹkọ́ àjeji gbá nyin kiri. Nitori o dara ki a mu nyin li ọkàn le nipa ore-ọfẹ, kì iṣe nipa onjẹ, ninu eyiti awọn ti o ti nrìn ninu wọn kò li ère. Awa ni pẹpẹ kan, ninu eyi ti awọn ti nsìn agọ́ kò li agbara lati mã jẹ. Nitoripe ara awọn ẹran wọnni, ẹ̀jẹ eyiti olori alufa mu wá si ibi mimọ́ nitori ẹ̀ṣẹ, a sun wọn lẹhin ibudo. Nitorina Jesu pẹlu, ki o le fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ sọ awọn enia di mimọ́, o jìya lẹhin bode. Nitorina ẹ jẹ ki a jade tọ̀ ọ lọ lẹhin ibudo, ki a mã rù ẹ̀gan rẹ̀. Nitoripe awa kò ni ilu ti o wà titi nihin, ṣugbọn awa nwá eyiti mbọ̀. Njẹ nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ ki a mã ru ẹbọ iyìn si Ọlọrun nigbagbogbo, eyini ni eso ète wa, ti njẹwọ orukọ rẹ̀. Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ. Ẹ mã gbọ ti awọn ti nṣe olori nyin, ki ẹ si mã tẹriba fun wọn: nitori nwọn nṣọ ẹṣọ nitori ọkàn nyin, bi awọn ti yio ṣe iṣíro, ki nwọn ki o le fi ayọ̀ ṣe eyi, li aisi ibinujẹ, nitori eyiyi yio jẹ ailere fun nyin. Ẹ mã gbadura fun wa: nitori awa gbagbọ pe awa ni ẹri-ọkàn rere, a si nfẹ lati mã wà lododo ninu ohun gbogbo. Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada. Njẹ Ọlọrun alafia, ẹniti o tun mu oluṣọ-agutan nla ti awọn agutan, ti inu okú wá, nipa ẹ̀jẹ majẹmu aiyeraiye, ani Oluwa wa Jesu, Ki o mu nyin pé ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rẹ̀, ki o mã ṣiṣẹ ohun ti iṣe itẹwọgba niwaju rẹ̀ ninu wa nipasẹ Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin. Emi si mbẹ nyin, ará, ẹ gbà ọ̀rọ iyanju mi; nitori iwe kukuru ni mo kọ si nyin. Ẹ mọ̀ pé a dá Timotiu arakunrin wa silẹ; bi o ba tete de, emi pẹlu rẹ̀ yio ri nyin. Ẹ kí gbogbo awọn ti nṣe olori nyin, ati gbogbo awọn enia mimọ́. Awọn ti o ti Itali wá kí nyin. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

Heb 13:1-25 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn onigbagbọ níláti fẹ́ràn ara wọn. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí nípa àlejò ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn angẹli lálejò láìmọ̀ pé angẹli ni wọ́n. Ẹ ranti àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, kí ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ̀yin náà wà lẹ́wọ̀n pẹlu wọn. Ẹ tún ranti àwọn tí à ń ni lára pẹlu, nítorí pé inú ayé ni ẹ wà sibẹ, irú nǹkan wọnyi lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin náà. Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè. Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé, “Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹ̀rù kò ní bà mí. Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.” Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn. Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani. A ní pẹpẹ ìrúbọ kan tí àwọn alufaa tí wọn ń sìn ninu àgọ́ ti ayé kò ní àṣẹ láti jẹ ninu ẹbọ rẹ̀. Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó. Bákan náà ni Jesu, ó jìyà lẹ́yìn odi ìlú kí ó lè sọ àwọn eniyan di mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà. Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa fún àwọn ẹlòmíràn ninu àwọn ohun ìní yín. Irú ẹbọ yìí ni inú Ọlọrun dùn sí. Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani. Ẹ máa gbadura fún wa. Ó dá wa lójú pé ọkàn wa mọ́. Ohun tí ó dára ni a fẹ́ máa ṣe nígbà gbogbo. Nítorí náà mo tún bẹ̀ yín gidigidi pé kí ẹ máa gbadura fún wa, kí wọ́n baà lè dá mi sílẹ̀ kíákíá láti wá sọ́dọ̀ yín. Kí Ọlọrun alaafia, ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde ninu òkú, Jesu, Olú olùṣọ́-aguntan, ẹni tí ó kú, kí ó baà lè fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe èdìdì majẹmu ayérayé, kí ó mu yín pé ninu gbogbo ohun rere kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa ṣe ohun tí ó wù ú ninu yín nípasẹ̀ Jesu Kristi ẹni tí ògo wà fún lae ati laelae. Amin. Mo bẹ̀ yín, ará, kí ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa yìí nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ si yín. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti dá Timoti, arakunrin wa, sílẹ̀: ó ti jáde lẹ́wọ̀n. Bí ó bá tètè dé, èmi ati òun ni a óo jọ ri yín. Ẹ kí gbogbo àwọn aṣiwaju yín ati gbogbo àwọn onigbagbọ. Àwọn ará láti Itali ki yín. Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu gbogbo yín.

Heb 13:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kí ìfẹ́ ará kí o wà títí. Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò; nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn angẹli ní àlejò láìmọ̀. Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara. Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí: Nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́. Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé, “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé, “Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù; kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?” Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn. Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè. Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ. Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó. Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀. Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níhìn-ín, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ. Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ. Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríba fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìṣirò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín. Ẹ máa gbàdúrà fún wa: nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà. Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùṣọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ayérayé, àní Olúwa wa Jesu. Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ́ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jesu Kristi; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín. Èmi sì ń bẹ̀ yín ará, ẹ gbà ọ̀rọ̀ ìyànjú mi; nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ sí yín. Ẹ mọ pé a sá titu Timotiu arákùnrin wa sílẹ̀; bí ó ba tètè dé, èmí pẹ̀lú rẹ̀ yóò rí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Ẹ ki gbogbo àwọn tí ń ṣe olórí yín, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Àwọn tí o ti Itali wá ki yín. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín.