Heb 12:27-29
Heb 12:27-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati ọ̀rọ yi, Lẹ̃kan si i, itumọ rẹ̀ ni mimu awọn ohun wọnni ti a nmì kuro, bi ohun ti a ti da, ki awọn ohun wọnni ti a kò le mì le wà sibẹ. Nitorina bi awa ti ngbà ilẹ ọba ti a kò le mì, ẹ jẹ ki a ni ore-ọfẹ nipa eyiti awa le mã sin Ọlọrun ni itẹwọgbà pẹlu ọ̀wọ ati ibẹru rẹ̀. Nitoripe Ọlọrun wa, iná ti ijonirun ni.
Heb 12:27-29 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti gba ìjọba tí kò ṣe é mì, ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọrun bí ó ti yẹ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ẹ̀rù; nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa.
Heb 12:27-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀. Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”