Heb 12:22-29

Heb 12:22-29 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan, ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé, ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ. Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.” Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti gba ìjọba tí kò ṣe é mì, ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọrun bí ó ti yẹ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ẹ̀rù; nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa.

Heb 12:22-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye, Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o Àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ. Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá: Ohùn ẹni tí ó mi ayé nígbà náà: ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.” Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀. Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”