Heb 12:1-6
Heb 12:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA bi a ti fi awọsanmọ ti o kún to bayi fun awọn ẹlẹri yí wa ká, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹ̀ṣẹ ti o rọrun lati dì mọ wa, ki a si mã fi sũru sure ije ti a gbé ka iwaju wa, Ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ́ wa; ẹni, nitori ayọ̀ ti a gbé ká iwaju rẹ̀, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ Ọlọrun. Sá ro ti ẹniti o farada irú isọrọ-odì yi lati ọdọ awọn ẹlẹṣẹ si ara rẹ̀, ki ẹ má ba rẹwẹsi ni ọkàn nyin, ki ãrẹ si mu nyin. Ẹnyin kò ìtĩ kọ oju ija si ẹ̀ṣẹ titi de ẹ̀jẹ ni ijakadi nyin. Ẹnyin si ti gbagbé ọ̀rọ iyanju ti mba nyin sọ bi ọmọ pe, Ọmọ mi, má ṣe alainani ibawi Oluwa, ki o má si ṣe rẹwẹsi nigbati a ba nti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wi: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi, a si mã nà olukuluku ọmọ ti o gbà.
Heb 12:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa. Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì. Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú. Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé, Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹ má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí. Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà, ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ, ni ó ń nà ní pàṣán.
Heb 12:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín. Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé, “Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa, kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí: Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí, a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”