Heb 12:1-29

Heb 12:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA bi a ti fi awọsanmọ ti o kún to bayi fun awọn ẹlẹri yí wa ká, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹ̀ṣẹ ti o rọrun lati dì mọ wa, ki a si mã fi sũru sure ije ti a gbé ka iwaju wa, Ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ́ wa; ẹni, nitori ayọ̀ ti a gbé ká iwaju rẹ̀, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ Ọlọrun. Sá ro ti ẹniti o farada irú isọrọ-odì yi lati ọdọ awọn ẹlẹṣẹ si ara rẹ̀, ki ẹ má ba rẹwẹsi ni ọkàn nyin, ki ãrẹ si mu nyin. Ẹnyin kò ìtĩ kọ oju ija si ẹ̀ṣẹ titi de ẹ̀jẹ ni ijakadi nyin. Ẹnyin si ti gbagbé ọ̀rọ iyanju ti mba nyin sọ bi ọmọ pe, Ọmọ mi, má ṣe alainani ibawi Oluwa, ki o má si ṣe rẹwẹsi nigbati a ba nti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wi: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi, a si mã nà olukuluku ọmọ ti o gbà. Ẹ mã mu suru labẹ ibawi: Ọlọrun mba nyin lo bi ọmọ ni; nitoripe ọmọ wo ni mbẹ ti baba ki ibawi? Ṣugbọn bi ẹnyin ba wà li aisi ibawi, ninu eyiti gbogbo enia ti jẹ alabapin, njẹ ọmọ àle ni nyin, ẹ kì isi iṣe ọmọ. Pẹlupẹlu awa ni baba wa nipa ti ara ti o ntọ́ wa, awa si mbù ọlá fun wọn: awa kì yio kuku tẹriba fun Baba awọn ẹmí ki a si yè? Nitori nwọn tọ́ wa fun ọjọ diẹ bi o ba ti dara loju wọn; ṣugbọn on fun ère wa, ki awa ki o le ṣe alabapin ìwa mimọ́ rẹ̀. Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ̀ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ̀, ani eso ododo. Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera; Ki ẹ si ṣe ipa-ọna ti o tọ fun ẹsẹ nyin, ki eyiti o rọ má bã kuro lori iké ṣugbọn ki a kuku wo o san. Ẹ mã lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ́, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa: Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe kùna ore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbòngbo ikorò kan ki o má ba hù soke ki o si yọ nyin lẹnu, ọ̀pọlọpọ a si ti ipa rẹ̀ di aimọ́; Ki o má bã si àgbere kan tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Esau, ẹniti o ti itori òkele onjẹ kan tà ogún ibí rẹ̀. Nitori ẹnyin mọ̀ pe lẹhinna ní ani nigbati o fẹ lati jogun ibukun na, a kọ̀ ọ (nitori kò ri aye ironupiwada) bi o tilẹ ti fi omije wá a gidigidi. Nitori ẹnyin kò wá si òke, ti a le fi ọwọ kàn, ati si iná ti njó, ati si iṣúdùdu ati òkunkun, ati iji, Ati iró ipè, ati ohùn ọ̀rọ, eyiti awọn ti o gbọ́ bẹ̀bẹ pe, ki a máṣe sọ ọ̀rọ si i fun wọn mọ́: Nitoripe ara wọn kò le gbà ohun ti o palaṣẹ, Bi o tilẹ jẹ ẹranko li o farakan òke na, a o sọ ọ li okuta, tabi a o gún u li ọ̀kọ pa. Iran na si lẹrù tobẹ̃, ti Mose wipe, ẹ̀ru bà mi gidigidi mo si warìri. Ṣugbọn ẹnyin wá si òke Sioni, ati si ilu Ọlọrun alãye, si Jerusalemu ti ọ̀run, ati si ẹgbẹ awọn angẹli ainiye, Si ajọ nla ati ìjọ akọbi ti a ti kọ orukọ wọn li ọ̀run, ati sọdọ Ọlọrun onidajọ gbogbo enia, ati sọdọ awọn ẹmí olõtọ enia ti a ṣe li aṣepé, Ati sọdọ Jesu alarina majẹmu titun, ati si ibi ẹ̀jẹ ibuwọ́n nì, ti nsọ̀rọ ohun ti o dara jù ti Abeli lọ. Kiyesi i, ki ẹ máṣe kọ̀ ẹniti nkilọ. Nitori bi awọn wọnni kò ba bọ́ nigbati nwọn kọ̀ ẹniti nkilọ li aiye, melomelo li awa kì yio bọ́ awa ti o pẹhinda si ẹniti nkilọ lati ọrun wá: Ohùn ẹniti o mì aiye nigbana: ṣugbọn nisisiyi o ti ṣe ileri, wipe, Lẹ̃kan si i emi kì yio mì kìki aiye nikan, ṣugbọn ọrun pẹlu. Ati ọ̀rọ yi, Lẹ̃kan si i, itumọ rẹ̀ ni mimu awọn ohun wọnni ti a nmì kuro, bi ohun ti a ti da, ki awọn ohun wọnni ti a kò le mì le wà sibẹ. Nitorina bi awa ti ngbà ilẹ ọba ti a kò le mì, ẹ jẹ ki a ni ore-ọfẹ nipa eyiti awa le mã sin Ọlọrun ni itẹwọgbà pẹlu ọ̀wọ ati ibẹru rẹ̀. Nitoripe Ọlọrun wa, iná ti ijonirun ni.

Heb 12:1-29 Yoruba Bible (YCE)

Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa. Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì. Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú. Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé, Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹ má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí. Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà, ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ, ni ó ń nà ní pàṣán. Ẹ níláti faradà á bí ìtọ́sọ́nà. Ọlọrun mú yín bí ọmọ ni. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí baba rẹ̀ kò ní tọ́ sọ́nà? Bí ẹ kò bá ní irú ìtọ́sọ́nà tí gbogbo ọmọ máa ń ní, á jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ tòótọ́. Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè? Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn baba wa nípa ti ara fi ń tọ́ wa, bí ó bá ti dára lójú wọn. Ṣugbọn Baba wa nípa ti ẹ̀mí ń tọ́ wa fún ire wa, kí á lè bá a pín ninu ìwà mímọ́ rẹ̀. Ní àkókò tí a bá ń sọ fún eniyan pé: má ṣe èyí, má ṣe tọ̀hún, kì í dùn mọ́ ẹni tí à ń tọ́. Pẹlu ìnira ni. Ṣugbọn ní ìgbẹ̀yìn a máa so èso alaafia ti ìgbé-ayé òdodo fún àwọn tí a bá ti tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ẹ gbé ọwọ́ yín tí kò lágbára sókè, ẹ mú kí eékún yín tí ń gbọ̀n di alágbára; ẹ ṣe ọ̀nà títọ́ fún ara yín láti máa rìn, kí ẹsẹ̀ tí ó bá ti rọ má baà yẹ̀, ṣugbọn kí ó lè mókun. Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má jẹ́ oníṣekúṣe tabi alaigbagbọ bíi Esau, tí ó tìtorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré ta anfaani tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àrólé baba rẹ̀. Ẹ mọ̀ pé nígbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gba ìre tí ó tọ́ sí àrólé, baba rẹ̀ ta á nù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wá ọ̀nà àtúnṣe, kò sí ààyè mọ́ fún ìrònúpìwàdà. Nítorí kì í ṣe òkè Sinai ni ẹ wá, níbi tí iná ti ń jó, tí ó ṣú dẹ̀dẹ̀ tí ó ṣókùnkùn tí afẹ́fẹ́ líle sì ń fẹ́, tí fèrè ń dún kíkankíkan, tí ohùn kan wá ń sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbọ́ ọ bẹ̀bẹ̀, pé kí àwọn má tún gbọ́ irú rẹ̀ mọ́. Nítorí ìjayà bá wọn nígbà tí a pàṣẹ fún wọn pé, “Bí ẹranko bá fi ara kan òkè náà, a níláti sọ ọ́ ní òkúta pa ni!” Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.” Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan, ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé, ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ. Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.” Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì. Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti gba ìjọba tí kò ṣe é mì, ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọrun bí ó ti yẹ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ẹ̀rù; nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa.

Heb 12:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín. Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé, “Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa, kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí: Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí, a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.” Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo. Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; “Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn. Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa: Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “gbòǹgbò ìkorò” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi. Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì. Àti ìró ìpè, àti ohùn ọ̀rọ̀, èyí tí àwọn tí o gbọ́ bẹ̀bẹ̀ pé, kí a má ṣe sọ ọ̀rọ̀ sí i fún wọn mọ́: Nítorí pé wọn kò lè gba ohun tí ó paláṣẹ, “Bí o tilẹ̀ jẹ ẹranko ni ó fi ara kan òkè náà, a ó sọ ọ́ ni òkúta.” Ìran náà sì lẹ́rù to bẹ́ẹ̀ tí Mose wí pé, “Ẹ̀rù ba mi gidigidi mo sì wárìrì.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wá sí òkè Sioni, àti sí ìlú Ọlọ́run alààyè, ti Jerusalẹmu ti ọ̀run, àti si ẹgbẹ́ àwọn angẹli àìníye, Si àjọ ńlá tí ìjọ àkọ́bí tí a ti kọ orúkọ wọn ni ọ̀run, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run onídàájọ́ gbogbo ènìyàn, àti sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀mí olóòtítọ́ ènìyàn tí a ṣe ni àṣepé, o Àti sọ́dọ̀ Jesu alárinà májẹ̀mú tuntun, àti si ibi ẹ̀jẹ̀ ìbùwọ́n ni, ti ń sọ̀rọ̀ ohun tí ó dára ju ti Abeli lọ. Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá: Ohùn ẹni tí ó mi ayé nígbà náà: ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.” Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀. Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a dá ọpẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀. Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”

Heb 12:1-29

Heb 12:1-29 YBCVHeb 12:1-29 YBCVHeb 12:1-29 YBCVHeb 12:1-29 YBCVHeb 12:1-29 YBCVHeb 12:1-29 YBCV