Heb 11:36-40
Heb 11:36-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati ti ìnà, ati ju bẹ̃ lọ ti ìde ati ti tubu: A sọ wọn li okuta, a fi ayùn rẹ́ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro; Awọn ẹniti aiye kò yẹ fun: nwọn nkiri ninu aṣálẹ, ati lori òke, ati ninu ihò ati ninu ihò abẹ ilẹ. Gbogbo awọn wọnyi ti a jẹri rere sí nipa igbagbọ́, nwọn kò si ri ileri na gbà: Nitori Ọlọrun ti pèse ohun ti o dara jù silẹ fun wa, pe li aisi wa, ki a má ṣe wọn pé.
Heb 11:36-40 Yoruba Bible (YCE)
A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n. A sọ àwọn mìíràn lókùúta. A fi ayùn rẹ́ àwọn mìíràn sí meji. A fi idà pa àwọn mìíràn. Àwọn mìíràn ń rìn kiri, wọ́n wọ awọ aguntan ati awọ ewúrẹ́, ninu ìṣẹ́ ati ìpọ́njú ati ìnira. Wọ́n dára ju kí wọ́n wà ninu ayé lọ. Wọ́n ń dá rìn kiri ninu aṣálẹ̀, níbi tí eniyan kì í gbé, lórí òkè, ninu ihò inú òkúta ati ihò inú ilẹ̀. Gbogbo àwọn wọnyi ni ẹ̀rí rere nípa igbagbọ, ṣugbọn wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí gbà. Nítorí pé àwa ni Ọlọrun ní lọ́kàn tí ó fi ṣe ètò tí ó dára jùlọ, pé kí àwa ati àwọn lè jọ rí ẹ̀kún ibukun gbà.
Heb 11:36-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú: A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró; Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀. Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́rìí rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà: Nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí ó dára jù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.