Heb 11:32-38
Heb 11:32-38 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ewo li emi o si tun mã wi si i? nitoripe ãyè kò ni tó fun mi lati sọ ti Gideoni, ati Baraku, ati Samsoni, ati Jefta; ti Dafidi, ati Samueli, ati ti awọn woli: Awọn ẹni nipasẹ igbagbọ́ ti nwọn ṣẹgun ilẹ ọba, ti nwọn ṣiṣẹ ododo, ti nwọn gbà ileri, ti nwọn dí awọn kiniun li ẹnu, Ti nwọn pa agbara iná, ti nwọn bọ́ lọwọ oju-idà, ti a sọ di alagbara ninu ailera, ti nwọn di akọni ni ìja, nwọn lé ogun awọn àjeji sá. Awọn obinrin ri okú wọn gbà nipa ajinde: a si dá awọn ẹlomiran lóro, nwọn kọ̀ lati gbà ìdasilẹ; ki nwọn ki o le ri ajinde ti o dara jù gbà: Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati ti ìnà, ati ju bẹ̃ lọ ti ìde ati ti tubu: A sọ wọn li okuta, a fi ayùn rẹ́ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro; Awọn ẹniti aiye kò yẹ fun: nwọn nkiri ninu aṣálẹ, ati lori òke, ati ninu ihò ati ninu ihò abẹ ilẹ.
Heb 11:32-38 Yoruba Bible (YCE)
Kí ni kí n tún wí? Àyè kò sí fún mi láti sọ nípa Gideoni, Baraki, Samsoni, Jẹfuta, Dafidi, Samuẹli ati àwọn wolii. Nípa igbagbọ, wọ́n ṣẹgun ilẹ̀ àwọn ọba, wọn ṣiṣẹ́ tí òdodo fi gbilẹ̀, wọ́n rí ìlérí Ọlọrun gbà. Wọ́n pa kinniun lẹ́nu mọ́. Wọ́n pa iná ńlá. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà. A sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọn kò ní ìlera. Wọ́n di akọni lójú ogun. Wọ́n tú àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ àjèjì ká tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá pada sẹ́yìn. Àwọn obinrin gba àwọn eniyan wọn tí wọ́n ti kú pada lẹ́yìn tí a ti jí wọn dìde kúrò ninu òkú. A dá àwọn mìíràn lóró títí wọ́n fi kú. Wọn kò pé kí á dá wọn sílẹ̀, nítorí kí wọ́n lè gba ajinde tí ó dára jùlọ. A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n. A sọ àwọn mìíràn lókùúta. A fi ayùn rẹ́ àwọn mìíràn sí meji. A fi idà pa àwọn mìíràn. Àwọn mìíràn ń rìn kiri, wọ́n wọ awọ aguntan ati awọ ewúrẹ́, ninu ìṣẹ́ ati ìpọ́njú ati ìnira. Wọ́n dára ju kí wọ́n wà ninu ayé lọ. Wọ́n ń dá rìn kiri ninu aṣálẹ̀, níbi tí eniyan kì í gbé, lórí òkè, ninu ihò inú òkúta ati ihò inú ilẹ̀.
Heb 11:32-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mi láti sọ ti Gideoni, àti Baraki, àti Samsoni, àti Jefta; àti Dafidi, àti Samuẹli, àti ti àwọn wòlíì: Àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tiwọn ṣẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ́ òdodo, tiwọn gba ìlérí, tiwọn dí àwọn kìnnìún lénu, Tí wọ́n pa agbára iná, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, tí wọ́n dí akọni nínú ìjà, wọ́n lé ogun àwọn àjèjì sá. Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà; Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú: A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró; Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.