Heb 11:23-29
Heb 11:23-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nipa igbagbọ́ ni awọn obi Mose pa a mọ́ fun oṣu mẹta nigbati a bí i, nitoriti nwọn ri i ni arẹwa ọmọ; nwọn kò si bẹ̀ru aṣẹ ọba. Nipa igbagbọ́ ni Mose, nigbati o dàgba, o kọ̀ ki a mã pè on li ọmọ ọmọbinrin Farao; O kuku yàn ati mã bá awọn enia Ọlọrun jìya, jù ati jẹ fãji ẹ̀ṣẹ fun igba diẹ; O kà ẹ̀gan Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ: nitoriti o nwo ère na. Nipa igbagbọ́ li o kọ̀ Egipti silẹ li aibẹ̀ru ibinu ọba: nitoriti o duro ṣinṣin bi ẹniti o nri ẹni airi. Nipa igbagbọ́ li o dá ase irekọja silẹ, ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ, ki ẹniti npa awọn akọbi ọmọ ki o má bã fi ọwọ́ kàn wọn. Nipa igbagbọ́ ni nwọn là okun pupa kọja bi ẹnipe ni iyangbẹ ilẹ: ti awọn ara Egipti danwò, ti nwọn si rì.
Heb 11:23-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Mose pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí tiwọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba. Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà. Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Ejibiti sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí. Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrékọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má bá a fi ọwọ́ kan wọn. Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la Òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.
Heb 11:23-29 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n bí Mose, nípa igbagbọ ni àwọn òbí rẹ̀ fi gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta nítorí wọ́n rí i pé ọmọ tí ó lẹ́wà ni, wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba. Nígbà tí Mose dàgbà tán, nípa igbagbọ ni ó fi kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n pe òun ní ọmọ ọmọbinrin Farao. Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ. Ó ka ẹ̀gàn nítorí Mesaya sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju gbogbo ìṣúra Ijipti lọ, nítorí ó ń wo èrè níwájú. Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn. Nípa igbagbọ ni ó fi ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ètò láti fi ẹ̀jẹ̀ ra ara ìlẹ̀kùn, kí angẹli tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ àwọn ará Ijipti má baà fọwọ́ kan ọmọ àwọn eniyan Israẹli. Nípa igbagbọ ni àwọn ọmọ Israẹli fi gba ààrin òkun pupa kọjá bí ìgbà tí eniyan ń rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn ará Ijipti náà gbìyànjú láti kọjá, rírì ni wọ́n rì sinu omi.