Heb 11:17-22
Heb 11:17-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a dán a wò, fi Isaaki rubọ: ẹniti o si ti fi ayọ̀ gbà ileri wọnni fi ọmọ-bíbi rẹ̀ kanṣoṣo rubọ. Niti ẹniti a wipe, Ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ: O si pari rẹ̀ si pe Ọlọrun tilẹ le gbe e dide, ani kuro ninu oku, ati ibiti o ti gbà a pada pẹlu ni apẹrẹ. Nipa igbagbọ́ ni Isaaki sure fun Jakọbu ati Esau niti ohun ti mbọ̀. Nipa igbagbọ́ ni Jakọbu, nigbati o nkú lọ, o súre fun awọn ọmọ Josefu ni ọ̀kọ̃kan; o si tẹriba, o simi le ori ọpá rẹ̀. Nipa igbagbọ́ ni Josefu, nigbati o nkú lọ, o ranti ìjadelọ awọn ọmọ Israeli; o si paṣẹ niti awọn egungun rẹ̀.
Heb 11:17-22 Yoruba Bible (YCE)
Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi Isaaki rúbọ nígbà tí Ọlọrun dán an wò. Ó fi ààyò ọmọ rẹ̀ rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún un nípa rẹ̀, tí Ọlọrun ti sọ fún un pé, “Láti inú Isaaki ni ìdílé rẹ yóo ti gbilẹ̀.” Èrò rẹ̀ ni pé Ọlọrun lè tún jí eniyan dìde ninu òkú. Nítorí èyí, àfi bí ẹni pé ó tún gba ọmọ náà pada láti inú òkú. Nípa igbagbọ ni Isaaki fi súre fún Jakọbu ati Esau tí ó sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn. Nígbà tí Jakọbu ń kú lọ, nípa igbagbọ ni ó fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Josẹfu. Ó ń sin Ọlọrun bí ó ti tẹríba lórí ọ̀pá rẹ̀. Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun.
Heb 11:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu, nígbà tí a dán an wò láti, fi Isaaki rú ẹbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kan ṣoṣo rú ẹbọ. Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀:” Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìde kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ́ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà. Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jakọbu, nígbà tí o ń ku lọ, ó súre fún àwọn ọmọ Josẹfu ni ọ̀kọ̀ọ̀kan; ó sì sinmi ní ìtẹríba lé orí ọ̀pá rẹ̀. Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀.