Heb 10:32-39
Heb 10:32-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹ ranti ọjọ iṣaju, ninu eyiti, nigbati a ti ṣí nyin loju, ẹ fi ara da wahala ijiya nla; Lapakan, nigbati a sọ nyin di iran wiwo nipa ẹ̀gan ati ipọnju; ati lapakan, nigbati ẹnyin di ẹgbẹ awọn ti a ṣe bẹ̃ si. Nitori ẹnyin bá awọn ti o wà ninu ìde kẹdun, ẹ si fi ayọ̀ gbà ìkolọ ẹrù nyin, nitori ẹnyin mọ̀ ninu ara nyin pe, ẹ ni ọrọ̀ ti o wà titi, ti o si dara ju bẹ̃ lọ li ọ̀run. Nitorina ẹ máṣe gbe igboiya nyin sọnu, eyiti o ni ère nla. Nitori ẹnyin kò le ṣe alaini sũru, nitori igbati ẹnyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan, ki ẹnyin ki o le gbà ileri na. Nitori niwọn igba diẹ si i, Ẹni nã ti mbọ̀ yio de, kì yio si jafara. Ṣugbọn olododo ni yio yè nipa igbagbọ́: ṣugbọn bi o ba fà sẹhin, ọkàn mi kò ni inu didùn si i. Ṣugbọn awa kò si ninu awọn ti nfà sẹhin sinu egbé; bikoṣe ninu awọn ti o gbagbọ́ si igbala ọkàn.
Heb 10:32-39 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ranti bí a ti ja ìjà líle, tí ẹ farada ìrora, látijọ́, nígbà tí ẹ kọ́kọ́ rí ìmọ́lẹ̀ igbagbọ. Nígbà mìíràn wọ́n fi yín ṣẹ̀sín, wọ́n jẹ yín níyà, àwọn eniyan ń fi yín ṣe ìran wò. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹ dúró láì yẹsẹ̀ pẹlu àwọn tí wọ́n ti jẹ irú ìyà bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n jìyà. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi gbà kí wọ́n fi agbára kó àwọn dúkìá yín lọ, nítorí ẹ mọ̀ pé ẹ ní dúkìá tí ó tún dára ju èyí tí wọn kó lọ, tí yóo sì pẹ́ jù wọ́n lọ. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìfọkàntán tí ẹ ní bọ́, nítorí ó ní èrè pupọ. Ohun tí ẹ nílò ni ìfaradà, kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, kí ẹ baà lè gba ìlérí tí ó ṣe. Nítorí náà, bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Nítorí láìpẹ́ jọjọ, ẹni tí ń bọ̀ yóo dé, kò ní pẹ́ rárá. Ṣugbọn àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ tèmi yóo wà láàyè nípa igbagbọ. Ṣugbọn bí èyíkéyìí ninu wọn bá fà sẹ́yìn inú mi kò ní dùn sí i.” Ṣugbọn àwa kò sí ninu àwọn tí wọn ń fà sẹ́yìn sí ìparun. Ṣugbọn àwa ní igbagbọ, a sì ti rí ìgbàlà.
Heb 10:32-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà; lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si. Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá. Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà. Nítorí, “Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé, kí yóò sì jáfara. Ṣùgbọ́n, “Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn, ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.” Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fàsẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.