Heb 10:26-29
Heb 10:26-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori bi awa ba mọ̃mọ̀ dẹṣẹ lẹhin igbati awa ba ti gbà ìmọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ mọ́, Bikoṣe ireti idajọ ti o ba ni lẹrù, ati ti ibinu ti o muná, ti yio pa awọn ọtá run. Ẹnikẹni ti o ba gàn ofin Mose, o kú li aisi ãnu nipa ẹri ẹni meji tabi mẹta: Melomelo ni ẹ ro pe a o jẹ oluwa rẹ̀ ni ìya kikan, ẹniti o ti tẹ Ọmọ Ọlọrun mọlẹ ti o si ti kà ẹ̀jẹ̀ majẹmu ti a fi sọ ọ di mimọ́ si ohun aimọ́, ti o si ti kẹgan Ẹmí ore-ọfẹ.
Heb 10:26-29 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Ohun tí ó kù ni pé kí á máa retí ìdájọ́ pẹlu ìpayà ati iná ńlá tí yóo pa àwọn ọ̀tá Ọlọrun. Bí ẹni meji tabi mẹta bá jẹ́rìí pé ẹnìkan ṣá Òfin Mose tì, pípa ni wọn yóo pa olúwarẹ̀ láì ṣàánú rẹ̀. Irú ìyà ńlá wo ni ẹ rò pé Ọlọrun yóo fi jẹ ẹni tí ó kẹ́gàn Ọmọ rẹ̀, tí ó rò pé nǹkan lásán ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí a fi yà á sọ́tọ̀, tí ó sì ṣe àfojúdi sí Ẹ̀mí tí a fi gba oore-ọ̀fẹ́?
Heb 10:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta: Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́.