Heb 10:22-23
Heb 10:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù. Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;)
Pín
Kà Heb 10Heb 10:22-23 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa. Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí.
Pín
Kà Heb 10Heb 10:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù. Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì; (nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí).
Pín
Kà Heb 10