Heb 10:19-25
Heb 10:19-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu, Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀; Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun; Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù. Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;) Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere: Ki a má mã kọ ipejọpọ̀ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mã gbà ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile.
Heb 10:19-25 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a ní ìgboyà láti wọ Ibi Mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ ìkélé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu, nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀. A tún ní alufaa àgbà tí ó wà lórí ìdílé Ọlọrun. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa. Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí. Ẹ jẹ́ kí á máa rò nípa bí a óo ti ṣe fún ara wa ní ìwúrí láti ní ìfẹ́ ati láti ṣe iṣẹ́ rere. Ẹ má jẹ́ kí á máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn mìíràn, ṣugbọn kí á máa gba ara wa níyànjú, pataki jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti rí i pé ọjọ́ ńlá ọ̀hún súnmọ́ tòsí.
Heb 10:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jesu, nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọjá aṣọ ìkélé èyí yìí ní, ara rẹ̀; àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run; ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù. Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì; (nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí). Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere: kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.