Heb 10:11-14
Heb 10:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati olukuluku alufa si nduro li ojojumọ́ o nṣe ìsin, o si nṣe ẹbọ kanna nigbakugba, ti kò le mu ẹ̀ṣẹ kuro lai: Ṣugbọn on, lẹhin igbati o ti ru ẹbọ kan fun ẹ̀ṣẹ titi lai, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; Lati igbà na lọ, ó nreti titi a o fi fi awọn ọtá rẹ̀ ṣe apoti itisẹ rẹ̀. Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai.
Heb 10:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà. Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀. Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae.
Heb 10:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti olúkúlùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkúgbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé: Ṣùgbọ́n òun, lẹ́yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; Láti ìgbà náà, ó retí títí a o fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀. Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.