Hag 2:9-23
Hag 2:9-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ogo ile ikẹhìn yi yio pọ̀ jù ti iṣãju lọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nihinyi li emi o si fi alafia fun ni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Li ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bère ofin lọwọ awọn alufa nisisiyi, pe, Bi ẹnikan ba rù ẹran mimọ́ ni iṣẹti aṣọ rẹ̀, ti o si fi iṣẹti aṣọ rẹ̀ kan àkara, tabi àṣaró, tabi ọti-waini, tabi ororo, tabi ẹrankẹran, yio ha jẹ mimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Bẹ̃kọ. Hagai si wipe, Bi ẹnikan ti o ba jẹ alaimọ́ nipa okú ba fi ara kan ọkan ninu wọnyi, yio ha jẹ alaimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Yio jẹ alaimọ́. Nigbana ni Hagai dahùn o si wipe, Bẹ̃ni enia wọnyi ri, bẹ̃ si ni orilẹ-ède yi ri niwaju mi, li Oluwa wi; bẹ̃ si li olukuluku iṣẹ ọwọ wọn; eyiti nwọn si fi rubọ nibẹ̀ jẹ alaimọ́. Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ rò lati oni yi de atẹhìnwa, ki a to fi okuta kan le ori ekeji ninu tempili Oluwa; Lati ọjọ wọnni wá, nigbati ẹnikan bã de ibi ile ogun, mẹwa pere ni: nigbati ẹnikan ba de ibi ifunti lati bã gbọ́n ãdọta akoto ninu ifunti na, ogún pere ni. Mo fi ìrẹdanù ati imúwòdu ati yìnyin lù nyin ninu gbogbo iṣẹ ọwọ nyin: ṣugbọn ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Nisisiyi ẹ rò lati oni lọ de atẹhìnwa, lati ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, ani lati ọjọ ti a ti fi ipilẹ tempili Oluwa sọlẹ, ro o. Eso ha wà ninu abà bi? lõtọ, àjara, ati igi òpọtọ, ati pomegranate, ati igi olifi, kò iti so sibẹ̀sibẹ̀: lati oni lọ li emi o bukún fun nyin. Ọ̀rọ Oluwa si tún tọ̀ Hagai wá li ọjọ kẹrinlelogun oṣù na pe, Sọ fun Serubbabeli, bãlẹ Juda, pe, emi o mì awọn ọrun ati aiye; Emi o si bì itẹ awọn ijọba ṣubu, emi o si pa agbara ijọba keferi run; emi o si doju awọn kẹkẹ́ de, ati awọn ti o gùn wọn; ati ẹṣin ati awọn ẹlẹṣin yio wá ilẹ; olukuluku nipa idà arakunrin rẹ̀. Li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o mu ọ, Iwọ Serubbabeli, iranṣẹ mi, ọmọ Ṣealtieli, li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di oruka edídi kan: nitoriti mo ti yàn ọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Hag 2:9-23 Yoruba Bible (YCE)
Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.” Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA sọ fún wolii Hagai pé, “Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ní kí o lọ bèèrè ìdáhùn lórí ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa. Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá mú ẹran tí a fi rúbọ, tí ó ti di mímọ́, tí ó dì í mọ́ ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀wù náà kan burẹdi, tabi àsáró, tabi waini, tabi òróró, tabi oúnjẹ-kóúnjẹ, ṣé ọ̀kan kan ninu àwọn oúnjẹ yìí lè tipa bẹ́ẹ̀ di mímọ́?” Àwọn alufaa bá dáhùn pé, “Rárá.” Nígbà náà ni Hagai tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá di aláìmọ́ nítorí pé ó farakan òkú, tí ó sì fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun tí a kà sílẹ̀ wọnyi ǹjẹ́ kò ní di aláìmọ́?” Wọ́n dáhùn pé: “Dájúdájú, yóo di aláìmọ́.” Hagai bá dáhùn, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi ati fún orílẹ̀-èdè yìí pẹlu iṣẹ́ ọwọ́ wọn níwájú OLUWA; gbogbo ohun tí wọ́n fi ń rúbọ jẹ́ aláìmọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí. OLUWA ní, “Nisinsinyii, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀ láti àkókò yìí lọ. Ẹ ranti bí ó ti rí fun yín kí ẹ tó fi ìpìlẹ̀ tẹmpili yìí lélẹ̀. Ninu oko tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí ogún òṣùnwọ̀n ọkà, mẹ́wàá péré ni ẹ rí; níbi tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí aadọta ìgò ọtí, ogún péré ni ẹ rí níbẹ̀. Mo kọlù yín, mo sì mú kí atẹ́gùn gbígbóná ati yìnyín wó ohun ọ̀gbìn yín lulẹ̀, sibẹsibẹ ẹ kò ronupiwada, kí ẹ pada sọ́dọ̀ mi. Lónìí ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ni ẹ fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀; láti òní lọ, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀. Kò sí ọkà ninu abà mọ, igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ kò sì tíì so; bẹ́ẹ̀ ni igi pomegiranate, ati igi olifi. Ṣugbọn láti òní lọ, n óo bukun yín.” Ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, OLUWA tún rán Hagai, pé kí ó sọ fún Serubabeli, gomina ilẹ̀ Juda pé òun OLUWA ní, “N óo mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì. N óo lé àwọn ìjọba kúrò ní ipò wọn; n óo sì ṣẹ́ àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè lápá. N óo ta kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n lókìtì. Ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n yóo ṣubú, wọn óo sì fi idà pa ara wọn. Ní ọjọ́ náà, n óo fi ìwọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ṣe aṣojú ninu ìjọba mi nítorí pé mo ti yàn ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”
Hag 2:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.” Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ wòlíì Hagai wá pé: “Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé: Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan àkàrà tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ” Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Nígbà náà ni Hagai wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?” Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.” Nígbà náà ni Hagai dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni OLúWA wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olúkúlùkù iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rú ẹbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́. “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili OLúWA. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òṣùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni OLúWA wí. ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili OLúWA lélẹ̀, rò ó dáradára: Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan. “ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ” OLúWA Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé: “Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé. Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run; Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.” OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.”