Hag 2:16-20
Hag 2:16-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lati ọjọ wọnni wá, nigbati ẹnikan bã de ibi ile ogun, mẹwa pere ni: nigbati ẹnikan ba de ibi ifunti lati bã gbọ́n ãdọta akoto ninu ifunti na, ogún pere ni. Mo fi ìrẹdanù ati imúwòdu ati yìnyin lù nyin ninu gbogbo iṣẹ ọwọ nyin: ṣugbọn ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Nisisiyi ẹ rò lati oni lọ de atẹhìnwa, lati ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, ani lati ọjọ ti a ti fi ipilẹ tempili Oluwa sọlẹ, ro o. Eso ha wà ninu abà bi? lõtọ, àjara, ati igi òpọtọ, ati pomegranate, ati igi olifi, kò iti so sibẹ̀sibẹ̀: lati oni lọ li emi o bukún fun nyin. Ọ̀rọ Oluwa si tún tọ̀ Hagai wá li ọjọ kẹrinlelogun oṣù na pe
Hag 2:16-20 Yoruba Bible (YCE)
Ninu oko tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí ogún òṣùnwọ̀n ọkà, mẹ́wàá péré ni ẹ rí; níbi tí ẹ tí ń retí pé ẹ óo rí aadọta ìgò ọtí, ogún péré ni ẹ rí níbẹ̀. Mo kọlù yín, mo sì mú kí atẹ́gùn gbígbóná ati yìnyín wó ohun ọ̀gbìn yín lulẹ̀, sibẹsibẹ ẹ kò ronupiwada, kí ẹ pada sọ́dọ̀ mi. Lónìí ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ni ẹ fi ìpìlẹ̀ tẹmpili lélẹ̀; láti òní lọ, ẹ kíyèsí ohun tí yóo máa ṣẹlẹ̀. Kò sí ọkà ninu abà mọ, igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ kò sì tíì so; bẹ́ẹ̀ ni igi pomegiranate, ati igi olifi. Ṣugbọn láti òní lọ, n óo bukun yín.” Ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, OLUWA tún rán Hagai, pé kí ó
Hag 2:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òṣùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni OLúWA wí. ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili OLúWA lélẹ̀, rò ó dáradára: Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan. “ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ” OLúWA Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé