Hag 2:1-9

Hag 2:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kọkanlelogun oṣù keje, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA tún sọ fún wolii Hagai, pé: “Tún lọ sọ́dọ̀ Serubabeli ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù, kí o bèèrè pé, ‘Àwọn wo ni wọ́n ṣẹ́kù ninu yín tí wọ́n rí i bí ẹwà ògo ilé yìí ti pọ̀ tó tẹ́lẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí i sí nisinsinyii? Ǹjẹ́ ó jẹ́ nǹkankan lójú yín? Ṣugbọn, mú ọkàn le, ìwọ Serubabeli, má sì fòyà, ìwọ Joṣua, ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa; ẹ ṣe ara gírí kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ náà ẹ̀yin eniyan; nítorí mo wà pẹlu yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí mo ṣe fun yín, nígbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, mo wà láàrin yín; nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ “Nítorí pé èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ ọ́ pé láìpẹ́, n óo tún mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì lẹ́ẹ̀kan sí i, ati òkun ati ilẹ̀. N óo mi gbogbo orílẹ̀-èdè, wọn óo kó ìṣúra wọn wá, n óo sì ṣe ilé yìí lọ́ṣọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí. Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà tí ó wà láyé; èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”

Hag 2:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ OLúWA wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai wí pé: “Sọ fún Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín? Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni OLúWA wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà;’ ni OLúWA wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ “Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. ‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ;’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.”