Hab 3:6-16

Hab 3:6-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

O duro, o si wọ̀n ilẹ aiye: o wò, o si mu awọn orilẹ-ède warìri; a si tú awọn oke-nla aiyeraiye ká, awọn òkèkékèké aiyeraiye si tẹba: ọ̀na rẹ̀ aiyeraiye ni. Mo ri agọ Kuṣani labẹ ipọnju: awọn aṣọ-ikele ilẹ̀ Midiani si warìri. Oluwa ha binu si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si okun, ti iwọ fi ngùn ẹṣin rẹ ati kẹkẹ́ igbàla rẹ? A ṣi ọrun rẹ̀ silẹ patapata, gẹgẹ bi ibura awọn ẹ̀ya, ani ọ̀rọ rẹ. Iwọ ti fi odò là ilẹ aiye. Awọn oke-nla ri ọ, nwọn si warìri: akúnya omi kọja lọ: ibú fọ̀ ohùn rẹ̀, o si gbe ọwọ́ rẹ̀ si oke. Õrùn ati oṣupa duro jẹ ni ibùgbe wọn: ni imọlẹ ọfà rẹ ni nwọn lọ, ati ni didán ọ̀kọ rẹ ti nkọ màna. Ni irúnu ni iwọ rìn ilẹ na ja, ni ibinu ni iwọ ti tẹ̀ awọn orilẹ-ede rẹ́. Iwọ jade lọ fun igbàla awọn enia rẹ, fun igbàla ẹni atororosi rẹ; iwọ ti ṣá awọn olori kuro ninu ile awọn enia buburu, ni fifi ipinlẹ hàn titi de ọrùn. Iwọ ti fi ọ̀pa rẹ̀ lu awọn olori iletò rẹ̀ já: nwọn rọ́ jade bi ãjà lati tu mi ka: ayọ̀ wọn ni bi ati jẹ talakà run nikọ̀kọ. Iwọ fi awọn ẹṣin rẹ rìn okun ja, okìti omi nla. Nigbati mo gbọ́, ikùn mi warìri; etè mi gbọ̀n li ohùn na; ibàjẹ wọ̀ inu egungun mi lọ, mo si warìri ni inu mi, ki emi ba le simi li ọjọ ipọnju: nigbati o ba goke tọ̀ awọn enia lọ, yio ke wọn kuro.

Hab 3:6-16 Yoruba Bible (YCE)

Ó dúró, ó wọn ayé; Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì; àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká, àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀. Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀. Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu, àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì. OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni, àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí, tabi òkun ni ò ń bá bínú, nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ, tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ? Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun, tí o fi ọfà lé ọsán ọrun; tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé. Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ, wọ́n wárìrì; àgbàrá omi wọ́ kọjá; ibú òkun pariwo, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè. Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn, nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò, tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà, bí wọ́n ti ń fò lọ. O la ayé kọjá pẹlu ibinu, o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀. O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là, láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là. O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú, o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn. O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun; àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líle láti tú wa ká, tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀. O fi àwọn ẹṣin rẹ tẹ òkun mọ́lẹ̀; wọ́n tẹ ríru omi mọ́lẹ̀. Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì, ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀; egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà, ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀. N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù.

Hab 3:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni. Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora. Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, OLúWA? Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí? Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun tí ìwọ fi ń gun ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ? A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé. Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ; ibú ń ké ramúramù ó sì gbé irú omi sókè. Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà. Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ. Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni ààmì òróró rẹ là; Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀ Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká: ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀. Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já, ó sì da àwọn omi ńlá ru. Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà; ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹsẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.