Hab 3:16-18
Hab 3:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati mo gbọ́, ikùn mi warìri; etè mi gbọ̀n li ohùn na; ibàjẹ wọ̀ inu egungun mi lọ, mo si warìri ni inu mi, ki emi ba le simi li ọjọ ipọnju: nigbati o ba goke tọ̀ awọn enia lọ, yio ke wọn kuro. Bi igi ọpọ̀tọ kì yio tilẹ tanná, ti eso kò si ninu àjara; iṣẹ igi-olifi yio jẹ aṣedanù, awọn oko kì yio si mu onje wá; a o ke agbo-ẹran kuro ninu agbo, ọwọ́ ẹran kì yio si si ni ibùso mọ: Ṣugbọn emi o ma yọ̀ ninu Oluwa, emi o ma yọ̀ ninu Ọlọrun igbàla mi.
Hab 3:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì, ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀; egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà, ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀. N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù. Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé, tí àjàrà kò sì so, tí kò sí èso lórí igi olifi; tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko, tí àwọn agbo aguntan run, tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́, sibẹsibẹ, n óo yọ̀ ninu OLUWA, n óo yọ̀ ninu Ọlọrun Olùgbàlà mi.
Hab 3:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà; ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹsẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá. Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná, tí èso kò sí nínú àjàrà; tí igi olifi ko le so, àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá; tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo, tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́, síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú OLúWA, èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.