Hab 1:12-13
Hab 1:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lati aiyeraiye ki iwọ ti wà? Oluwa Ọlọrun mi, Ẹni Mimọ́ mi? awa kì yio kú. Oluwa, iwọ ti yàn wọn fun idajọ; Ọlọrun alagbara, iwọ ti fi ẹsẹ̀ wọn mulẹ fun ibawi. Oju rẹ mọ́ jù ẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò ìwa-ìka: nitori kini iwọ ha ṣe nwò awọn ti nhùwa arekerekè, ti o si pa ẹnu rẹ mọ, nigbati ẹni-buburu jẹ ẹniti iṣe olododo jù u run?
Hab 1:12-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ṣebí láti ayérayé ni o ti wà? Ọlọrun mi, Ẹni Mímọ́ mi, a kò ní kú. OLUWA, ìwọ ni o yan àwọn ará Babiloni gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́. Ìwọ Àpáta, ni o gbé wọn kalẹ̀ bíi pàṣán, láti jẹ wá níyà. Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi o kò lè gba ohun tí kò tọ́. Kí ló wá dé tí o fi ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí o sì dákẹ́, tí ò ń wo àwọn ẹni ibi níran tí wọn ń run àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ.
Hab 1:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà? OLúWA Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú OLúWA, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́; Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi; ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè? Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?