Hab 1:1-11

Hab 1:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀rọ-ìmọ ti Habakuku wolii rí. Oluwa, emi o ti ke pẹ to, ti iwọ kì yio fi gbọ́! ti emi o kigbe si ọ, niti ìwa-ipa, ti iwọ kì yio si gbalà! Ẽṣe ti o mu mi ri aiṣedede, ti o si jẹ ki nma wò ìwa-ìka? nitori ikógun ati ìwa-ipá wà niwaju mi: awọn ti si nrú ijà ati ãwọ̀ soke mbẹ. Nitorina li ofin ṣe di ẹ̀rọ, ti idajọ kò si jade lọ li ẹtọ́; nitoriti ẹni buburu yí olododo ka; nitorina ni idajọ ẹbi ṣe njade. Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin. Nitoripe, wò o, emi gbe awọn ara Kaldea dide, orilẹ-ède ti o korò, ti o si yára, ti yio rìn ibú ilẹ na ja, lati ni ibùgbe wọnni, ti kì iṣe ti wọn. Nwọn ni ẹ̀ru, nwọn si fò ni laiyà: idajọ wọn, ati ọlanla wọn, yio ma ti inu wọn jade. Ẹṣin wọn pẹlu yara jù ẹkùn lọ, nwọn si muná jù ikõkò aṣãlẹ lọ: ẹlẹṣin wọn yio si tàn ara wọn ka, ẹlẹṣin wọn yio si ti ọ̀na jijìn rére wá; nwọn o si fò bi idì ti nyára lati jẹun. Gbogbo wọn o si wá fun ìwa-ipá; iwò oju wọn o si wà siwaju, nwọn o si kó igbèkun jọ bi yanrìn. Nwọn o si ma fi awọn ọba ṣẹsín, awọn ọmọ alade yio si di ẹni-ẹ̀gan fun wọn: gbogbo ibi agbara ni nwọn o si fi rẹrin; nitoripe nwọn o ko erupẹ̀ jọ, nwọn o si gbà a. Nigbana ni inu rẹ̀ yio yipadà, yio si rekọja, yio si ṣẹ̀, ni kikà agbara rẹ̀ yi si iṣẹ òriṣa rẹ̀.

Hab 1:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ìran tí Ọlọrun fihan wolii Habakuku nìyí. OLUWA, yóo ti pẹ́ tó, tí n óo máa ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́; tí o kò sì ní dá mi lóhùn? Tí n óo máa ké pé, “Wo ìwà ipá!” tí o kò sì ní gba olúwarẹ̀ sílẹ̀? Kí ló dé tí o fi ń jẹ́ kí n máa rí àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí o jẹ́ kí n máa rí ìyọnu? Ìparun ati ìwà ipá wà níwájú mi, ìjà ati aáwọ̀ sì wà níbi gbogbo. Òfin kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́ òdodo. Àwọn ẹni ibi dòòyì ká olódodo, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ òdodo po. Ọlọrun ní: “Wo ààrin àwọn orílẹ̀-èdè yíká, O óo rí ohun ìjọjú yóo sì yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí mò ń ṣe nǹkan ìyanu kan ní àkókò rẹ, tí o kò ní gbàgbọ́ bí wọ́n bá sọ fún ọ. Wò ó! N óo gbé àwọn ará Kalidea dìde, orílẹ̀-èdè tí ó yára, tí kò sì ní àánú; àwọn tí wọ́n la ìbú ayé já, tí wọn ń gba ilẹ̀ onílẹ̀ káàkiri. Ìrísí wọn bani lẹ́rù; wọ́n ń fi ọlá ńlá wọn ṣe ìdájọ́ bí ó ti wù wọ́n. “Àwọn ẹṣin wọn yára ju àmọ̀tẹ́kùn lọ, wọ́n burú ju ìkookò tí ebi ń pa ní àṣáálẹ́ lọ. Pẹlu ìgbéraga ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn máa ń gun ẹṣin wọn lọ. Dájúdájú, ọ̀nà jíjìn ni àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ti ń wá; wọn a fò, bí idì tí ń sáré sí oúnjẹ. “Tìjàtìjà ni gbogbo wọn máa ń rìn, ìpayà á bá gbogbo eniyan bí wọ́n bá ti ń súnmọ́ tòsí. Wọn a kó eniyan ní ìgbèkùn, bí ẹni kó yanrìn nílẹ̀. Wọn a máa fi àwọn ọba ṣe ẹlẹ́yà, wọn a sì sọ àwọn ìjòyè di àmúṣèranwò. Wọn a máa fi àwọn ìlú olódi ṣe ẹlẹ́yà, nítorí òkítì ni wọ́n mọ sí ara odi wọn, wọn a sì gbà wọ́n. Wọn a fẹ́ wá bí ìjì, wọn a sì tún fẹ́ lọ, àwọn olubi eniyan, tí agbára wọn jẹ́ ọlọrun wọn.”

Hab 1:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Habakuku rí. OLúWA, èmi yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi? Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!” ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà? Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédéé Èéṣe tí ìwọ sì fi ààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú. Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí. Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà. OLúWA “Ẹ wo inú àwọn kèfèrí, ki ẹ sí wòye, Kí háà kí ó sì ṣe yin gidigidi. Nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin. Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Babeli dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú-fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe tiwọn. Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà, ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn, Yóò máa ti inú wọn jáde. Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ, wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká; wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré, wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú; wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn. Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé. Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín; Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà, yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”