Gẹn 7:11-24

Gẹn 7:11-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

Li ẹgbẹta ọdún ọjọ́ aiye Noa, li oṣù keji, ni ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù, li ọjọ́ na ni gbogbo isun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun si ṣí silẹ. Òjo na si wà lori ilẹ li ogoji ọsán on ogoji oru. Li ọjọ́ na gan ni Noa wọ̀ inu ọkọ̀, ati Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti, awọn ọmọ Noa, ati aya Noa, (ati awọn aya ọmọ rẹ̀ mẹta pẹlu wọn). Awọn, ati gbogbo ẹranko ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin gbogbo ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ nla ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ abiyẹ. Nwọn si wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀, meji meji ninu ẹda gbogbo, ninu eyiti ẹmi ìye wà. Awọn ti o si wọle lọ, nwọn wọle ti akọ ti abo ninu ẹdá gbogbo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. OLUWA si sé e mọ́ ile. Ikún-omi si wà li ogoji ọjọ́ lori ilẹ; omi si nwú si i, o si mu ọkọ̀ fó soke, o si gbera kuro lori ilẹ. Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi. Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ. Omi gbilẹ soke ni igbọ́nwọ mẹ̃dogun; a si bò gbogbo okenla mọlẹ. Gbogbo ẹdá ti nrìn lori ilẹ si kú, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ati gbogbo enia: Gbogbo ohun ti ẹmi ìye wà ni ihò imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si kú. Ohun alãye gbogbo ti o wà lori ilẹ li a si parun, ati enia, ati ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun, nwọn si run kuro lori ilẹ. Noa nikan li o kù, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Omi si gbilẹ li aiye li ãdọjọ ọjọ́.

Gẹn 7:11-24 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keji ọdún tí Noa di ẹni ẹgbẹta (600) ọdún, ni orísun alagbalúgbú omi tí ó wà ninu ọ̀gbun ńlá lábẹ́ ilẹ̀ ya, tí gbogbo fèrèsé omi tí ó wà ní ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀, òjò sì rọ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti ati aya rẹ̀ ati àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta; pẹlu àwọn ẹranko ati àwọn ẹran ọ̀sìn, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati oniruuru àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè patapata ni wọ́n wọ inú ọkọ̀ tọ Noa lọ ní meji meji. Gbogbo àwọn ohun ẹlẹ́mìí, akọ kan, abo kan, ní oríṣìí kọ̀ọ̀kan wọlé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Noa. OLUWA bá ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ náà. Ìkún omi wà lórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́. Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi léfòó lójú omi. Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i ni ọkọ̀ náà ń lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí rẹ̀. Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi bo gbogbo àwọn òkè gíga tí wọ́n wà láyé mọ́lẹ̀. Ó sì tún pọ̀ sí i títí tí ó fi ga ju àwọn òkè gíga lọ ní igbọnwọ mẹẹdogun (mita 7). Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n kú patapata, ati ẹyẹ, ati ẹran ọ̀sìn, ati ẹranko, ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà ati eniyan. Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń mí lórí ilẹ̀ ayé patapata ni wọ́n kú. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe pa gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé run: gbogbo eniyan, gbogbo ẹranko, gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati ẹyẹ. Noa nìkan ni kò kú ati àwọn tí wọ́n jọ wà ninu ọkọ̀ pẹlu rẹ̀. Aadọjọ (150) ọjọ́ gbáko ni omi fi bo gbogbo ilẹ̀.

Gẹn 7:11-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀. Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀. Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, OLúWA sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀. Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi. Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù. Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́ (150).