Gẹn 50:20-21
Gẹn 50:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là. Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.
Gẹn 50:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere, kí ó lè dá ẹ̀mí ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n wà láàyè lónìí sí. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù, n óo máa tọ́jú ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, tí ó sì dá wọn lọ́kànle.
Gẹn 50:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbèrò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbèrò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò pèsè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.” Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn.