Gẹn 50:1-26
Gẹn 50:1-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
JOSEFU si ṣubu lé baba rẹ̀ li oju, o si sọkun si i lara, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. Josefu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn oniṣegun, ki nwọn ki o kùn baba on li ọṣẹ: awọn oniṣegun si kùn Israeli li ọṣẹ. Nwọn si kún ogoji ọjọ́ fun u; nitoripe bẹ̃li a ikún ọjọ́ awọn ti a kùn li ọṣẹ: awọn ara Egipti si ṣọ̀fọ rẹ̀ li ãdọrin ọjọ́. Nigbati ọjọ́ ọ̀fọ rẹ̀ kọja, Josefu sọ fun awọn ara ile Farao pe, Njẹ bi emi ba ri ore-ọfẹ li oju nyin emi bẹ̀ nyin, ẹ wi li eti Farao pe, Baba mi mu mi bura wipe, Kiyesi i, emi kú: ni isà mi ti mo ti wà fun ara mi ni ilẹ Kenaani, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o sin mi. Njẹ nitorina emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o goke lọ, ki emi ki o si lọ isin baba mi, emi o si tun pada wá. Farao si wipe, Goke lọ, ki o si sin okú baba rẹ, gẹgẹ bi o ti mu ọ bura. Josefu si goke lọ lati sin baba rẹ̀: ati gbogbo awọn iranṣẹ Farao, ati awọn àlagba ile rẹ̀, ati gbogbo awọn àlagba ilẹ Egipti si bá a goke lọ. Ati gbogbo awọn ara ile Josefu, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ara ile baba rẹ̀: kìki awọn ọmọ wẹ́wẹ wọn, ati ọwọ́-ẹran wọn, ati ọwọ́-malu wọn, ni nwọn fi silẹ ni ilẹ Goṣeni. Ati kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin si bá a goke lọ: ẹgbẹ nlanla si ni ẹgbẹ na. Nwọn si dé ibi ilẹ ipakà Atadi, ti o wà li oke Jordani, nibẹ̀ ni nwọn si gbé fi ohùn rére ẹkún nlanla ṣọ̀fọ rẹ̀: o si ṣọ̀fọ fun baba rẹ̀ li ọjọ́ meje. Nigbati awọn ara ilẹ na, awọn ara Kenaani, si ri ọ̀fọ na ni ibi ilẹ ipakà Atadi, nwọn wipe, Ọ̀fọ nla li eyi fun awọn ara Egipti: nitorina ni nwọn ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Abel-misraimu, ti o wà loke odò Jordani. Awọn ọmọ rẹ̀ si ṣe bi o ti fi aṣẹ fun wọn: Nitori ti awọn ọmọ rẹ̀ mú u lọ si ilẹ Kenaani, nwọn si sin i ninu ihò oko Makpela, ti Abrahamu rà pẹlu oko fun iní ilẹ isinku, lọwọ Efroni ara Hitti, niwaju Mamre. Josefu si pada wá si Egipti, on ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o bá a goke lọ lati sin baba rẹ̀, lẹhin ti o ti sin baba rẹ̀ tán. Nigbati awọn arakunrin Josefu ri pe baba wọn kú tán, nwọn wipe, Bọya Josefu yio korira wa, yio si gbẹsan gbogbo ibi ti a ti ṣe si i lara wa. Nwọn si rán onṣẹ tọ̀ Josefu lọ wipe, Baba rẹ ti paṣẹ ki o tó kú pe, Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u. Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ pẹlu, nwọn wolẹ niwaju rẹ̀: nwọn si wipe, Wò o, iranṣẹ rẹ li awa iṣe. Josefu si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: emi ha wà ni ipò Ọlọrun? Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ibi li ẹnyin rò si mi; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọ si rere, lati mu u ṣẹ, bi o ti ri loni lati gbà ọ̀pọlọpọ enia là. Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn. Josefu si joko ni Egipti, on ati ile baba rẹ̀: Josefu si wà li ãdọfa ọdún. Josefu si ri awọn ọmọloju Efraimu ti iran kẹta; awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse li a si gbé kà ori ẽkun Josefu pẹlu. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi kú: Ọlọrun yio si bẹ̀ nyin wò nitõtọ, yio si mú nyin jade kuro ni ilẹ yi, si ilẹ ti o ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu. Josefu si mu awọn ọmọ Israeli bura, wipe, Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò nitõtọ, ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lati ihin lọ. Bẹ̃ni Josefu kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún: nwọn si kùn u li ọṣẹ, a si tẹ́ ẹ sinu posi ni Egipti.
Gẹn 50:1-26 Yoruba Bible (YCE)
Josẹfu dojúbo òkú baba rẹ̀ lójú, ó sọkún, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Lẹ́yìn náà, Josẹfu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn pé kí wọ́n fi òògùn tí wọ́n fi máa ń tọ́jú òkú, tí kì í fíí bàjẹ́, tọ́jú òkú baba òun. Wọ́n fi òògùn yìí tọ́jú òkú Jakọbu. Ogoji ọjọ́ gbáko ni àwọn oníṣègùn máa fi ń tọ́jú irú òkú bẹ́ẹ̀. Àwọn ará Ijipti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún aadọrin ọjọ́. Nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Josẹfu sọ fún àwọn ará ilé Farao pé, “Ẹ jọ̀wọ́, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ bá mi sọ fún Farao pé, baba mi mú mi búra nígbà tí àtikú rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, pé, ‘Nígbà tí mo bá kú, ninu ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani, ni kí ẹ sin mí sí.’ Nítorí náà, kí Farao jọ̀wọ́, fún mi láàyè kí n lọ sin òkú baba mi, n óo sì tún pada wá.” Farao dáhùn, ó ní, “Lọ sin òkú baba rẹ gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún un.” Josẹfu lọ sin òkú baba rẹ̀, gbogbo àwọn iranṣẹ Farao sì bá a lọ, ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà ààfin ọba, ati gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú Ijipti, ati gbogbo ìdílé Josẹfu àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀, àfi àwọn ọmọde, àwọn agbo ẹran, ati àwọn mààlúù nìkan ni ó kù sí ilẹ̀ Goṣeni. Kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin bá a lọ pẹlu, àwọn eniyan náà pọ̀ lọpọlọpọ. Nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Atadi, níwájú Jọdani, wọ́n pohùnréré ẹkún, Josẹfu sì ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ meje. Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani. Àwọn ọmọ Jakọbu sin òkú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sinu ihò òkúta tí ó wà ninu oko Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, tí Abrahamu rà mọ́ ilẹ̀ tí ó rà lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti láti fi ṣe itẹ́ òkú. Nígbà tí Josẹfu sin òkú baba rẹ̀ tán, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n bá a lọ. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i pé baba àwọn ti kú, wọ́n ní, “Ó ṣeéṣe kí Josẹfu kórìíra wa, kí ó sì gbẹ̀san gbogbo ibi tí a ti ṣe sí i.” Wọ́n bá ranṣẹ sí Josẹfu pé, “Baba rẹ ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ kí ó tó kú pé, ‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún. Àwọn arakunrin rẹ̀ náà sì wá, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Wò ó, a di ẹrú rẹ.” Ṣugbọn Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, èmi kì í ṣe Ọlọrun. Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere, kí ó lè dá ẹ̀mí ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n wà láàyè lónìí sí. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù, n óo máa tọ́jú ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, tí ó sì dá wọn lọ́kànle. Josẹfu sì ń gbé ilẹ̀ Ijipti, òun ati ìdílé baba rẹ̀, ó gbé aadọfa (110) ọdún láyé. Josẹfu rí ìran kẹta ninu àwọn ọmọ Efuraimu. Àwọn ọmọ tí Makiri ọmọ Manase bí, ọwọ́ Josẹfu ni ó bí wọn sí pẹlu. Josẹfu sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Àtikú mi kù sí dẹ̀dẹ̀, ṣugbọn Ọlọrun yóo máa tọ́jú yín, yóo sì mu yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún Abrahamu ati Isaaki ati Jakọbu.” Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra fún un pé, nígbà tí Ọlọrun bá mú wọn pada sí ilẹ̀ Kenaani, wọn yóo kó egungun òun lọ́wọ́ lọ. Josẹfu kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n fi òògùn tọ́jú òkú rẹ̀ kí ó má baà bàjẹ́, wọ́n sì tẹ́ ẹ sinu pósí ní ilẹ̀ Ijipti.
Gẹn 50:1-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Josẹfu sì ṣubú lé baba rẹ̀, ó sọkún, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́. Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Josẹfu wí fún àwọn ará ilé Farao pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bá mi sọ fún Farao. ‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú: sinmi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ” Farao wí pé, “Gòkè lọ, kí o sì sin baba rẹ, bí ó tí mú ọ búra.” Báyìí ni Josẹfu gòkè lọ láti sìnkú baba rẹ̀. Gbogbo àwọn ìjòyè Farao ni ó sìn ín lọ—àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà ilẹ̀ Ejibiti. Yàtọ̀ fún gbogbo àwọn ará ilé Josẹfu àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ ilé baba rẹ̀, àwọn ọmọ wọn nìkan àti agbo ẹran pẹ̀lú agbo màlúù ni ó sẹ́ kù ní Goṣeni. Kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin pẹ̀lú gòkè lọ. Àìmoye ènìyàn ni ó lọ. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ ìpakà Atadi, ní ẹ̀bá Jordani, wọn pohùnréré ẹkún; Níbẹ̀ ni Josẹfu sì tún dúró ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí ń gbé níbẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Atadi, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Ejibiti ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Misraimu (Ìṣọ̀fọ̀ àwọn ará Ejibiti). Kò sì jìnnà sí Jordani. Báyìí ni àwọn ọmọ Jakọbu ṣe ohun tí baba wọn pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makpela, ní tòsí i Mamre tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti, pẹ̀lú ilẹ̀ náà. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Josẹfu padà sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀. Nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu rí i pé baba wọn kú, wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ bí ó bá ṣe pé Josẹfu ṣì fi wá sínú ńkọ́, tí ó sì fẹ́ gbẹ̀san gbogbo aburú tí a ti ṣe sí i?” Nítorí náà wọ́n ránṣẹ́ sí Josẹfu wí pé, “Baba rẹ fi àṣẹ yìí sílẹ̀ kí ó tó lọ wí pé: ‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Josẹfu: Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjì àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Josẹfu sọkún. Àwọn arákùnrin rẹ̀ wá, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n wí pé, “Ẹrú rẹ ni a jẹ́.” Ṣùgbọ́n Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbèrò láti ṣe mi ní ibi, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbèrò láti fi ṣe rere tí ń ṣe lọ́wọ́ yìí; ni gbígba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn là. Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò pèsè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.” Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn. Josẹfu sì ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀. Ó sì wà láààyè fún àádọ́fà (110) ọdún. Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Efraimu-Àwọn ọmọ Makiri, ọmọkùnrin Manase ni a sì gbé le eékún Josẹfu nígbà tí ó bí wọn. Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.” Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra májẹ̀mú kan wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín.” Báyìí ni Josẹfu kú nígbà tí ó pé àádọ́fà (110) ọdún. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ṣe òkú rẹ̀ lọ́jọ̀ tan, a gbé e sí inú pósí ní Ejibiti.