Gẹn 5:28-32
Gẹn 5:28-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lameki si wà li ọgọsan ọdún o lé meji, o si bí ọmọkunrin kan: O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe, Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lãla ọwọ́ wa, nitori ilẹ ti OLUWA ti fibú. Lameki si wà li ẹgbẹta ọdún o dí marun, lẹhin ti o bí Noa, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: Gbogbo ọjọ́ Lameki si jẹ ẹgbẹrin ọdún o dí mẹtalelogun: o si kú. Noa si jẹ ẹni ẹ̃dẹgbẹta ọdún: Noa si bí Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.
Gẹn 5:28-32 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Lamẹki di ẹni ọdún mejilelọgọsan-an (182), ó bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Noa, ó ní: “Eléyìí ni yóo mú ìtura wá fún wa ninu iṣẹ́ ati wahala wa tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi gégùn-ún.” Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin. Gbogbo ọdún tí Lamẹki gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mẹtadinlọgọrin (777) kí ó tó kú. Nígbà tí Noa di ẹni ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún, ó bí Ṣemu, Hamu ati Jafẹti.
Gẹn 5:28-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án (182) ni ó bí ọmọkùnrin kan. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi gégùn ún.” Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ó-dínmárùn-ún ọdún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún ó-dínmẹ́tàlélógún (777), ó sì kú. Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500) ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.